ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Maa Baa Lọ ni Rírìn Ninu Imọlẹ ati Ifẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • Ẹ Maa Baa Lọ ni Rírìn Ninu Imọlẹ ati Ifẹ

      Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Johanu Kìn-ínní

      JEHOFA ni Orisun imọlẹ ati ifẹ. Awa gbọdọ wo Ọlọrun fun imọlẹ tẹmi. (Saamu 43:3) Ifẹ sì jẹ ọkan lara awọn èso ẹmi mimọ rẹ̀.—Galatia 5:22, 23.

      Imọlẹ, ifẹ, ati awọn nǹkan miiran ni a jiroro ninu lẹta apọsteli Johanu akọkọ ti a misi, ti o ṣeeṣe ki a kọ ni tabi lẹbaa Efesu ni nǹkan bii 98 C.E. Idi pataki fun kikọ ọ ni lati daabobo awọn Kristian kuro lọwọ ipẹhinda ki a sì ran wọn lọwọ lati maa baa lọ ni ririn ninu imọlẹ. Niwọn bi a ti ndojukọ awọn ipenija nipa ifẹ, igbagbọ, ati ipawatitọ mọ́ wa otitọ, ayẹwo lẹta yii dajudaju yoo ṣanfaani fun wa.

      ‘Rìn ninu Imọlẹ’

      Johanu mu ki o ṣe kedere pe awọn Kristian oluṣotitọ gbọdọ rìn ninu imọlẹ tẹmi. (1:1–2:29) Oun wipe: “Imọlẹ ni Ọlọrun, òkùnkùn kankan kò sí [ko si ohun ti nṣe ibi, ìwà palapala, aijootọ, tabi àìmọ́] lọdọ rẹ̀ rara.” Nitori naa awọn Kristian ẹni ami ororo ti a fi ẹmi yàn ‘nrin ninu imọlẹ,’ wọn ni “ipin” pẹlu Ọlọrun, Kristi, ati araawọn. Awọn pẹlu ni a ti wẹ̀nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ nipasẹ ẹ̀jẹ̀ Jesu.

      Yala awa jẹ Kristian ẹni ami-ororo pẹlu ireti ti ọrun tabi awa nfojusọna fun iye ayeraye lori ilẹ-aye, awa yoo maa baa lọ lati janfaani lati inu irubọ Jesu kiki bi awa ba fẹran awọn arakunrin wa ṣugbọn kii ṣe aye. Awa pẹlu gbọdọ yẹra fun didi ẹni ti a nipa le lori nipasẹ awọn apẹhinda, iru awọn bii “aṣodisi Kristi,” awọn ti wọn sẹ́ Baba ati Ọmọkunrin. Ki awa ma sì ṣe gbagbe lae pe iye ayeraye ni awọn wọnni ti wọn rọ̀mọ́ otitọ ti wọn sì sọ ododo dàṣà yoo gbadun.

      Awọn Ọmọ Ọlọrun Fi Ìfẹ́ Hàn

      Lẹhin naa Johanu fi awọn ọmọ Ọlọrun hàn yatọ. (3:1–4:21) Fun ohun kan, wọn nṣe ohun ti o jẹ ododo. Awọn pẹlu nṣegbọran si aṣẹ Jehofa Ọlọrun ‘pe wọn ni igbagbọ ninu orukọ Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti wọn sì fẹran ara wọn ẹnikinni keji.’

      Eniyan kan ti o ni “ìmọ̀ Ọlọrun” mọ̀ nipa awọn ète Jehofa ati bi a ṣe fi ifẹ Rẹ̀ han. Eyi nilati ran ẹni naa lọwọ lati fi ifẹ hàn. Nitootọ, “ẹni ti ko ba ni ifẹ kò mọ Ọlọrun; nitori pe ifẹ ni Ọlọrun.” Ifẹ atọrunwa ni a fihan nigba ti Ọlọrun “ran ọmọ rẹ̀ lati jẹ etutu fun ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Bi Jehofa ba fẹran wa lọna ti o gbooro bayii, o jẹ aigbọdọmaṣe fun wa lati fẹran ẹnikinni keji. Bẹẹni, ẹnikẹni ti o sọ pe oun fẹran Ọlọrun gbọdọ nifẹẹ arakunrin rẹ̀ nipa tẹmi pẹlu.

      Igbagbọ ‘Ṣẹgun Aye’

      Ifẹ sun awọn ọmọ Ọlọrun lati pa awọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ṣugbọn nipa igbagbọ ni wọn fi lè ‘ṣẹgun aye.’ (5:1-21) Igbagbọ wa ninu Ọlọrun, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ati Ọmọkunrin rẹ̀ mu ki o ṣeeṣe fun wa lati ‘ṣẹgun aye’ nipa kikọ ironu ti ko tọna ati awọn ọna rẹ̀ silẹ ati nipa pipa awọn àṣẹ Jehofa mọ. Ọlọrun ti fun ‘awọn oluṣẹgun aye’ ni ireti naa fun iye ayeraye ti o sì ngbọ awọn adura wọn ti o wà ni ibamu pẹlu ifẹ inu rẹ. Nitori pe ẹnikẹni “ti a bí nipa ti Ọlọrun” kii dẹṣẹ, Satani kii nawọ́ gán iru awọn ẹni bawọnyi. Ṣugbọn awọn ti wọn jẹ ẹni ami-ororo ati awọn iranṣẹ Jehofa ti wọn ni ireti ti ilẹ aye nilati ranti pe ‘gbogbo aye wà labẹ agbara ẹni buburu nì.’

  • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | April 15
    • Ẹ Rìn Gẹgẹ Bi Awọn Alajumọṣiṣẹpọ Ninu Otitọ

      Awọn Koko Itẹnumọ lati inu Johanu Keji ati Ikẹta

      ÌMỌ̀ otitọ jẹ ami idanimọ fun awọn olujọsin Jehofa. (Johanu 8:31, 32; 17:17) Ririn ninu otitọ atọrunwa ṣe koko fun igbala. Awọn iranṣẹ Ọlọrun sì gbọdọ jẹ alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.

      Lẹta keji ati ikẹta apọsteli Johanu ti a misi sọrọ nipa “ririn ninu otitọ.” (2 Johanu 4; 3 Johanu 3, 4) Johanu ikẹta pẹlu fun ifọwọsowọpọ ni iṣiri gẹgẹ bi “awọn alajumọṣiṣẹpọ ninu otitọ.” (3 Johanu 5-8) O ṣeeṣe ki a kọ awọn lẹta mejeeji ni Efesu tabi nitosi rẹ̀ ni nǹkan bii 98 C.E. Ṣugbọn awọn ohun ti wọn sọ lè ṣanfaani fun awọn eniyan Jehofa lonii.

      Johanu Keji Tẹnumọ Otitọ

      Johanu keji kọkọ tẹnumọ otitọ ati ifẹ o sì kilọ lodisi “awọn aṣodisi Kristi.” (Ẹsẹ 1-7) Lẹta naa ni a dari si “ayanfẹ obinrin ọlọla” boya eniyan kan. Ṣugbọn bi a ba ti fi ranṣẹ si ijọ, “awọn ọmọ” rẹ̀ jẹ awọn Kristian ti a fi ẹ̀mí bí “ti a yàn” nipasẹ Ọlọrun fun iye ti ọrun. (Roomu 8:16, 17; Filipi 3:12-14) Johanu yọ̀ pe awọn kan bayii “nrin ninu otitọ” ti wọn tipa bayii dena ipẹhinda. Sibẹsibẹ, aini wà fun wọn lati ṣọra lodisi awọn “aṣodisi Kristi,” ti wọn sẹ́ pe Jesu wá ninu ẹran ara. Awọn Ẹlẹrii Jehofa lonii nkọbiara si iru awọn ikilọ bawọnyi lodisi ipẹhinda.

      Johanu funni ni imọran tẹle e lori biba awọn apẹhinda lo ó sì pari lẹta rẹ̀ lẹhin naa pẹlu idaniyanfẹ ati awọn ikini ti ara-ẹni. (Ẹsẹ 8-13) Nipa iru awọn làálàá gẹgẹ bi wiwaasu, oun ati awọn miiran ti mu eso ti nyọrisi iyilọkan pada awọn wọnni ti oun fi lẹta rẹ̀ ranṣẹ si jade, kiki nipa ‘kikiyesara’ fun ara wọn nipa tẹmi ni wọn yoo to lè “ri èrè kikun gbà,” ti o ni “adé” ti ọrun ninu lọna hihan gbangba eyi ti a pamọ́ fun awọn ẹni ami-ororo oluṣotitọ. (2 Timoti 4:7, 8) Bi ẹnikẹni ‘ti kò duro ninu ẹkọ Kristi’ ba tọ̀ wọn wá, wọn ‘kò nilati gbà á sinu ile wọn tabi kí i’ ki wọn baa lè yẹra fun jijẹ alajumọ kẹgbẹ pọ ninu “awọn iṣẹ́ buburu” rẹ̀. Lẹhin sisọ ireti naa pe oun yoo wá ki oun sì ba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ wọnni sọrọ pọ ni ojukoju, Johanu pari lẹta rẹ̀ pẹlu awọn ikini.

      Johanu Kẹta Tẹnumọ Ifọwọsowọpọ

      Johanu Kẹta ni a dari rẹ̀ si Gayọsi o sì kọkọ ṣakiyesi nǹkan ti oun nṣe fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀. (Ẹsẹ 1-8) Gayọsi “nrin ninu otitọ” nipa didirọ mọ́ gbogbo awọn ẹkọ Kristian pata. Oun tun “nṣe iṣẹ igbagbọ” pẹlu ninu ṣiṣetilẹhin fun awọn arakunrin olubẹwo. Johanu kọwe pe: “Awa . . . wa labẹ aigbọdọmaṣe lati gba iru awọn ẹni bẹẹ pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe, ki awa baa le di alajumọ ṣiṣẹ pọ ninu otitọ.” Awọn Ẹlẹrii Jehofa nnawọ ẹmi alejo ṣiṣe ti o farajọ eyi si awọn alaboojuto arinrin ajo lonii.

      Lẹhin ṣiṣe ifiwera iwa buburu Diotirefe pẹlu ti Demetiriọsi, Johanu pari lẹta rẹ̀. (Ẹsẹ 9-14) Diotirefe tí nwa ògo kò fi ọ̀wọ̀ eyikeyii hàn fun Johanu ani o tilẹ gbiyanju lati le awọn wọnni ti wọn ngba awọn arakunrin pẹlu ẹmi alejo ṣiṣe kuro ninu ijọ paapaa. Ṣugbọn, Demetiriọsi kan bayii ni a tọkasi gẹgẹ bi apẹẹrẹ rere. Johanu nireti lati ri Gayọsi laipẹ o sì pari rẹ̀ pẹlu ikini ati idaniyanfẹ pe ki Gayọsi gbadun alaafia.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́