ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fún Àwùjọ Ní Ìṣírí Àti Okun
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
    • Fìdùnnú Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tí Ọlọ́run Ń Gbé Ṣe Nísinsìnyí. Nígbà tí o bá ń wá ọ̀nà láti fún àwọn arákùnrin rẹ níṣìírí, pàfiyèsí wọn sí ohun tí Jèhófà ń ṣe nísinsìnyí. Tí o bá sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n dùn mọ́ ọ, wàá mú kí irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀ sọ lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ pẹ̀lú.

      Wo àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti lè máa forí ti àwọn pákáǹleke inú ìgbésí ayé. Ó ń fọ̀nà tó dára jú lọ láti gbà gbé ìgbésí ayé hàn wá. (Aísá. 30:21) Ó ṣàlàyé ohun tó fa ìwà ọ̀daràn, àìsí-ìdájọ́-òdodo, ipò òṣì, àìsàn àti ikú fún wa, ó sì sọ bí òun yóò ṣe mú gbogbo ìwọ̀nyí wá sópin. Ó mú ká wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará onífẹ̀ẹ́. Ó fún wa láǹfààní iyebíye ti àdúrà gbígbà. Ó gbé àǹfààní jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. Ó là wá lójú láti rí i pé Kristi ti gorí ìtẹ́ ní ọ̀run àti pé òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan búburú yìí ti dé tán.—Ìṣí. 12:1-12.

      Fi àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè wa kún àwọn ìbùkún wọ̀nyí pẹ̀lú. Bí o bá sọ̀rọ̀ àwọn ìpèsè wọ̀nyí lọ́nà tó fi hàn pé o mọrírì wọn tọkàntọkàn, wàá jẹ́ kí ìpinnu àwọn yòókù láti máa pàdé pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ará túbọ̀ lágbára sí i.—Héb. 10:23-25.

      Àwọn ìròyìn tó ń fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà ń bù kún ìsapá wa lóde ẹ̀rí tún ń fúnni lókun pẹ̀lú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n ń mú “ìdùnnú ńlá bá gbogbo àwọn ará” bí wọ́n ṣe ń sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń yí padà di Kristẹni. (Ìṣe 15:3) Ìwọ náà lè mú ìdùnnú bá àwọn ará nípa sísọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró fún wọn.

      Tó o bá mú kí olúkúlùkù àwọn ará rí bí ohun tí wọ́n ń ṣe ti ṣe pàtàkì tó á tún fún wọn láfikún ìṣírí. Yìn wọ́n fún ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Yin àwọn tó jẹ́ pé ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn kò jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn tó nǹkan mọ́ síbẹ̀ tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ fara dà á nìṣó. Rán wọn létí pé Jèhófà kò gbàgbé ìfẹ́ tí wọ́n ti fi hàn fún orúkọ rẹ̀. (Héb. 6:10) Bí ìgbàgbọ́ ẹni bá dúró gbọn-in gbọn-in nígbà ìdánwò, ohun iyebíye lonítọ̀hún ní yẹn. (1 Pét. 1:6, 7) Àwọn ará nílò irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀.

      Sọ̀rọ̀ Tinútinú Nípa Ìrètí Ọjọ́ Iwájú. Àwọn ìlérí tí Ọlọ́run mí sí, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ń bọ̀ wá, jẹ́ orísun ìṣírí pàtàkì fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ràn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ tiẹ̀ lè ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyẹn lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n fífi tí o fi ìmọrírì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí yìí lè mú kí o sọ ìlérí wọ̀nyí dọ̀tun lọ́kàn wọn. O lè mú kí ó túbọ̀ dá wọn lójú pé wọ́n á ṣẹ, kí o sì mú kí wọ́n túbọ̀ mọrírì rẹ̀ gidigidi lọ́kàn wọn. Bí o bá ń fi ohun tó o ti kọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò wàá lè ṣe èyí.

      Ọ̀gá ni Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ nínú fífún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ìṣírí àti Òkun. Síbẹ̀, o ṣì lè bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti rí i pé àwọn èèyàn rẹ̀ rí ìṣírí àti okun yìí gbà. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nínú ìjọ, lo àǹfààní náà láti jẹ́ kí wọ́n rí ìṣírí àti okun gbà.

  • Máa Bá Ìtẹ̀síwájú Rẹ Nìṣó
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
    • Máa Bá Ìtẹ̀síwájú Rẹ Nìṣó

      ǸJẸ́ ìwọ bí ẹnì kan tíì ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìmọ̀ràn inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ yìí látòkèdélẹ̀? Ǹjẹ́ o sì ti ṣe gbogbo ìdánrawò tí a dámọ̀ràn rẹ̀ tán pátá? Ǹjẹ́ ò ń fi kókó kọ̀ọ̀kan sílò nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, yálà ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí ní àwọn ìpàdé yòókù àti nígbà tí o bá wà lóde ẹ̀rí?

      Máa bá a lọ láti jàǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Láìka bó ṣe wù kó ti pẹ́ tó tí o ti ń bá ọ̀rọ̀ sísọ bọ̀, àwọn ibi tí wàá ti lè tẹ̀ síwájú sí i ṣì wà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́