-
Ẹ Wa Ni Sẹpẹ fun Ọjọ Jehofa!Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
-
-
Ẹ Wa Ni Sẹpẹ fun Ọjọ Jehofa!
Awọn Kókó Itẹnumọ Lati Inu Tẹsalonika Kìn-ínní
ỌJỌ Jehofa! Awọn Kristian ni Tẹsalonika igbaani ronu pe o ti ku si dẹdẹ. Wọn ha tọna bi? Nigba wo ni yoo de? Iyẹn jẹ ọran pataki kan ti a bojuto ninu lẹta akọkọ apọsteli Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, ti a fi ranṣẹ lati Kọrinti ni nnkan bii ọdun 50 ti Sanmanni Tiwa.
Pọọlu ati Sila fidii ijọ mulẹ ni Tẹsalonika, ibujokoo ti ipinlẹ akoso Romu ti Masidonia. (Iṣe 17:1-4) Lẹhin naa, ninu lẹta rẹ akọkọ si awọn ara Tẹsalonika, Pọọlu sọ ọrọ iwuri, pese iṣileti, o si jiroro ọjọ Jehofa. Awa pẹlu le janfaani lati inu lẹta yii, paapaa bi ọjọ Jehofa ti sunmọle nisinsinyi gan an.
Funni ni Ọrọ Iwuri ati Iṣiri
Pọọlu kọkọ fun awọn ara Tẹsalonika ni ọrọ iwuri. (1:1-10) Ọrọ iwuri yẹ nitori iṣẹ iṣotitọ ati ifarada wọn. O yẹ fun ọrọ iwuri pẹlu, pe wọn “gba ọrọ naa ninu ipọnju ọpọlọpọ, pẹlu ayọ Ẹmi Mimọ.” Iwọ nha fun awọn ẹlomiran ni ọrọ iwuri gẹgẹbi Pọọlu ti ṣe bi?
Apọsteli naa ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ. (2:1-12) Laika ihuwasi alafojudi ni Filippi si, oun ti ‘ni igboya ninu Ọlọrun lati sọrọ ihinrere’ fun awọn ara Tẹsalonika. Oun ti yẹ apọnle, ojukokoro, ati wiwa ogo silẹ. Pọọlu ko di ẹru-inira amuni nawonara ṣugbọn o jẹ ẹni pẹlẹ pẹlu wọn gẹgẹbi abiyamọ ti jẹ pẹlu ọmọ rẹ. Ẹ wo apẹẹrẹ rere kan ti o jẹ́ fun awọn alagba lonii!
Awọn ọ̀rọ̀ Pọọlu ti o tẹle e fun awọn ara Tẹsalonika ni iṣiri lati duro gbọnyingbọnyin nigbati a ba nṣe inunibini si wọn. (2:13–3:13) Wọn ti farada inunibini lati ọdọ awọn ara ilu wọn, Timoti si ti mu irohin rere wa fun Pọọlu nipa ipo tẹmi wọn. Apọsteli naa gbadura pe ki wọn pọ gidigidi ninu ifẹ ati pe ki a ṣe awọn ọkan-aya wọn giri. Lọna ti o farajọra, Ẹlẹrii Jehofa nisinsinyi gbadura fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti a nṣe inunibini si, wọn nfun wọn ni iṣiri bi o ba ṣeeṣe, wọn sì nyọ ninu awọn irohin iṣotitọ wọn.
Duro Ni Wiwa Lojufo nipa Tẹmi!
Awọn ara Tẹsalonika gba imọran tẹle e. (4:1-18) Wọn nilati rin lọna kikun sii ni ipa ọna ti o wu Ọlọrun, fifi ifẹ ara hansode sii ati ṣiṣiṣẹ pẹlu ọwọ araawọn lati kaju aini wọn. Ju bẹẹ lọ, wọn nilati tu araawọn ẹnikinni ẹnikeji ninu pẹlu ireti naa pe ni igba wíwànihin in Jesu awọn onigbagbọ ti a fi ẹmi yan ti wọn ti ku ni a o kọ́kọ́ gbedide ti wọn yoo si sopọṣọkan pẹlu rẹ̀. Lẹhin igba naa, awọn ẹni ami ororo ti wọn walaaye nigba iku ati ajinde wọn yoo darapọ mọ Kristi ati awọn wọnni ti a ti jinde si iye ti ọrun ṣaaju.
Pọọlu jiroro ọjọ Jehofa tẹle e o si pese imọran siwaju sii. (5:1-28) Ọjọ Jehofa nbọ gẹgẹ bi ole, pẹlu iparun ojiji ti o daju lẹhin igbe naa: “Alaafia ati ailewu!” Nitori naa awọn ara Tẹsalonika nilati wa lojufo nipa tẹmi niṣo, ti a daabobo wọn nipasẹ àwo ìgbàyà ti igbagbọ ati ifẹ ati nipasẹ ireti ti igbala gẹgẹ bi àṣíborí. Wọn nilati ni ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun awọn wọnni ti wọn nṣe alaga ninu ijọ wọn si nilati fasẹhin kuro ninu iwa buruku, gẹgẹ bi awa ti gbọdọ ṣe.
Lẹta Pọọlu akọkọ si awọn ara Tẹsalonika nilati ta wa ji lati fi ọrọ iwuri ati iṣiri fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa. O nilati tun sun wa lati jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu iwa ati iṣesi. Dajudaju imọran rẹ̀ sì le ran wa lọwọ lati wa ni sẹpẹ fun ọjọ Jehofa.
-
-
“Ẹ Maṣe Juwọsilẹ Ninu Ṣiṣe Ohun Ti O Tọna”Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
-
-
“Ẹ Maṣe Juwọsilẹ Ninu Ṣiṣe Ohun Ti O Tọna”
Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati inu Tẹsalonika Keji
ANIYAN apọsteli Pọọlu fun awọn Kristian ni ilu nla Masidonia ti Tẹsalonika sun un lati kọ lẹta rẹ̀ keji si wọn, ni nnkan bii 51 C.E. Awọn kan ninu ijọ nsọ laitọ pe wíwànihin in Jesu Kristi ku si dẹ̀dẹ̀. Ani boya lẹta kan ti a kasi ti Pọọlu lọna aitọ ni a tumọsi gẹgẹ bi eyi ti nfihan pe “ọjọ Jehofa” ti de.—2 Tẹsalonika 2:1, 2.
Nitorinaa ironu awọn ara Tẹsalonika diẹ nbeere fun itunṣe bọsipo. Ninu lẹta rẹ keji, Pọọlu gboriyin fun wọn fun igbagbọ wọn ti ndagba, ifẹ ti npọ sii ati ifarada oluṣotitọ. Ṣugbọn oun tun fihan pe ipẹhinda yoo wa ṣaaju wiwa nihin-in Jesu. Nitori naa awọn akoko iṣoro nbẹ niwaju, lẹta apọsteli naa yoo si ran wọn lọwọ lati kọbiarasi iṣileti rẹ: “Ẹ maṣe juwọsilẹ ninu ṣiṣe ẹtọ.” (2 Tẹsalonika 3:13) Awọn ọrọ Pọọlu le ran wa lọwọ ni ọna kan naa.
Iṣipaya ati Wiwa Nihin-in Jesu
Pọọlu kọkọ sọrọ nipa itura alaafia kuro ninu ipọnju. (1:1-12) Eyi yoo wá “nigba iṣipaya Jesu Oluwa lati ọrun wa pẹlu awọn alagbara angeli rẹ.” Iparun ayeraye ni a o muwa nigba naa sori awọn wọnni ti wọn kii ṣegbọran si ihinrere. O ntunininu lati ranti eyi nigba ti a ba njiya ipọnju lọwọ awọn oninunibini.
Lẹhin eyi, Pọọlu tọkajade pe “ọkunrin iwa ailofin” naa ni a o ṣipaya ṣaaju wiwa nihin-in Kristi. (2:1-17) Awọn ara Tẹsalonika ni a ko nilati rusoke nipa ihin iṣẹ eyikeyii ti nmu un wa sọkan pe “ọjọ Jehofa” ti de ba wọn na. Lakọọkọ, ipẹhinda naa yoo waye ti a o si ṣí ọkunrin iwa ailofin naa paya. Lẹhin igba naa, Jesu yoo sọ ọ di asan, ni ṣiṣe bẹẹ ni igba ifihan wiwa nihin-in Rẹ̀. Laaarin akoko naa, Pọọlu gbadura pe ki Ọlọrun ati Kristi tu ọkan-aya awọn ara Tẹsalonika ninu ki o si mu wọn “fidi mulẹ ṣinṣin ninu iṣe ati ọ̀rọ̀ daradara gbogbo.”
Biba Awọn Oníségesège Lò
Laaarin awọn ọrọ Pọọlu siwaju sii ni awọn itọni lori biba awọn eniyan oníségesège lò. (3:1-18) Oun fi igbọkanle han pe Oluwa yoo fun awọn ara Tẹsalonika lokun yoo si pa wọn mọ kuro lọwọ ẹni buruku naa, Satani Eṣu. Ṣugbọn wọn nilo lati gbe igbesẹ fun anfaani tiwọn funraawọn nipa tẹmi. Wọn nilati fasẹhin kuro lọdọ awọn oníségesège, awọn wọnni ti wọn ntojubọ awọn ọran tí kò kan wọn ti wọn sì nkọ lati ṣiṣẹ. Pọọlu wipe, “Bi ẹnikẹni ko ba fẹ ṣiṣẹ, ki o ma si ṣe jẹun.” Iru awọn ẹni bẹẹ ni a nilati samisi, ko gbọdọ si ibakẹgbẹ ajọṣe kankan pẹlu wọn, bi o tilẹ jẹ pe a nilati gba wọn niyanju gẹgẹ bi ará. Awọn Kristian oluṣotitọ ara Tẹsalonika ni wọn ko nilati juwọsilẹ ninu ṣiṣe ohun ti o tọ, Pọọlu si nifẹẹ ọkan pe ki inurere ailẹtọọsi Oluwa Jesu Kristi wa pẹlu gbogbo wọn.
Lẹta Pọọlu keji si awọn ara Tẹsalonika fun awọn Ẹlẹrii Jehofa ni idaniloju pe itura alaafia kuro ninu ipọnju wọn yoo de nigbati Kristi ati awọn angẹli rẹ ba mu ẹsan wa sori awọn wọnni ti wọn ko ṣegbọran si ihin rere. O tun nfun igbagbọ lokun lati mọ pe “ọkunrin iwa ailofin naa” (ẹgbẹ awujọ alufaa Kristendom) ati gbogbo isin eke ni a o muwa si opin laipẹ jọjọ. Ki o to di ìgbà naa, ẹ jẹ ki a kọbiarasi igbaniniyanju Pọọlu pe kí á má juwọsilẹ ninu ṣiṣe ẹtọ.
-