ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Di Igbagbọ ati Ẹri-ọkan Rere Mu
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
    • Ẹ Di Igbagbọ ati Ẹri-ọkan Rere Mu

      Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati Inu Timoti Kìn-ínní

      NI NNKAN bii 56 C.E., apọsteli Pọọlu kilọ fun awọn alagba ijọ ni Efesu pe “ikooko buburu” yoo dide laaarin wọn yoo si maa “sọrọ òdì, lati fa awọn ọmọ ẹhin sẹhin wọn.” (Iṣe 20:29, 30) Ni awọn ọdun diẹ, ẹkọ ipẹhinda ti wá lewu rinlẹ debi pe Pọọlu rọ Timoti lati ja ija ogun tẹmi ninu ijọ lati pa ìmọ́gaara rẹ̀ mọ́ ki o si ran awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ lọwọ lati duro ninu igbagbọ. Iyẹn ni lajori idi ti Pọọlu fi kọ lẹta rẹ akọkọ si Timoti lati Masidonia ni nnkan bii 61-64 C.E.

      Timoti ni a fun ni itọni nipa awọn ila-iṣẹ alagba, ati àyè ti Ọlọrun yan fun awọn obinrin, awọn ẹ̀rí ìtóótun ti awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ ojiṣẹ, ati awọn ọran miiran. Irufẹ itọni bẹẹ tun ṣanfaani lonii.

      Igbaniniyanju si Igbagbọ

      Pọọlu beere pẹlu imọran lati di igbagbọ ati ẹri ọkan rere mu. (1Ti 1:1-20) Oun fun Timoti ni iṣiri lati duro ni Efesu ki o si “paṣẹ fun awọn kan, ki wọn ki o maṣe kọni ni ẹkọ miiran.” Pọọlu fi imoore han fun iṣẹ ojiṣẹ ti a yan fun un, ni gbigba pe oun ti fi aimọkan ati aini igbagbọ huwa nigba ti oun ṣe inunibini si awọn ọmọlẹhin Jesu. Aposteli naa paṣẹ fun Timoti lati maa baa lọ ni jija ija ogun tẹmi ‘didi igbagbọ ati ẹri ọkan rere mu’ ki o ma si dabi awọn wọnni ti wọn “rì ọkọ̀ igbagbọ wọn.”

      Imọran lori Ijọsin

      Lẹhin naa, Pọọlu funni ni imọran gẹgẹ bi “olukọ awọn keferi [“orilẹ ede,” NW] ní igbagbọ ati otitọ.” (2:1-15) Awọn adura ni a nilati gba fun awọn wọnni ti wọn wà ni ipo giga ki awọn Kristian baa le maa gbe ni alaafia. O jẹ ifẹ inu Ọlọrun pe ki a gba oriṣiriṣi eniyan la, ẹkọ pataki kan si ni pe Kristi “fi araarẹ ṣe irapada fun gbogbo eniyan.” Pọọlu fihan pe obinrin kan nilati ṣe araarẹ lọṣọọ niwọntunwọnsi ko si gbọdọ lo ọla-aṣẹ lori ọkunrin.

      Ijọ ni a gbọdọ ṣetojọ daradara. (3:1-16) Nitori naa Pọọlu ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ẹri ìtóótun awọn alaboojuto ati iranṣẹ iṣẹ ojiṣẹ. Lati inu awọn ohun ti apọsteli naa kọ, Timoti yoo wá mọ bí oun yoo ṣe dari ara oun ninu ijọ naa, “ọwọ̀n ati ìpìlẹ̀ [“itilẹhin,” NW] otitọ.”

      Pọọlu fun Timoti ni imọran ara ẹni lati ran an lọwọ lati ṣọra fun ẹkọ èké. (4:1-16) Ni awọn akoko ọjọ iwaju awọn kan yoo ṣubu kuro ninu igbagbọ. Ṣugbọn nipa fifiyesi ara rẹ̀ ati ẹkọ rẹ̀ leralera, Timoti yoo ‘gba ara rẹ̀ ati awọn ti ngbọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ là.’

      Timoti tun gba imọran lori biba awọn ẹni kọọkan lò, èwe ati àgbà. (5:1-25) Fun apẹẹrẹ, awọn ìpèsè yiyẹ ni a nilati ṣe fun awọn àgbà opó ti wọn ni orukọ Kristian rere. Dipo ṣíṣòfófó, awọn ọ̀dọ́ opó nilati ṣegbeyawo ki wọn si bi awọn ọmọ. Awọn agba ọkunrin ti wọn nṣakoso ni ọna rere ni a nilati kà kun awọn ti o yẹ fun ọlá ilọpo meji.

      Ifọkansin Oniwa-bi-Ọlọrun Pẹlu Ẹmi Ohun Moní Tómi

      Imọran lori ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun ni o pari lẹta Pọọlu. (6:1-21, NW) “Ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun papọ pẹlu ẹmi ohun moní tómi” jẹ ọna èrè ńlá, ṣugbọn ipinnu lati di ọlọrọ maa nṣamọna si iparun yán-ányán-án. Pọọlu rọ Timoti lati ja ija rere ti igbagbọ ati ‘ki o di iye ainipẹkun mu ṣinṣin.’ Lati le di iye tootọ yẹn mú, awọn ọlọ́rọ̀ nilati “gbe ireti wọn, kii ṣe lori ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun.”

  • Ẹ Gbáralé Okun Tí Ọlọrun Fifúnni
    Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | January 15
    • Ẹ Gbáralé Okun Tí Ọlọrun Fifúnni

      Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati Inu Timoti Keji

      JEHOFA fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ní agbara lati farada awọn adanwo ati inunibini. Bawo sì ni Timoti ati awọn Kristian miiran ṣe nilo okun ti Ọlọrun fifunni to! Iná run Romu bajẹ ni 64 C.E., àhesọ si sọ pe Olu-ọba Nero ni o fà á. Lati daabobo araarẹ̀, oun dẹbi fun awọn Kristian, eyi ni kedere sún ìgbì inunibini kan bẹrẹ. O ṣeeṣe pe ni akoko yẹn (ni nnkan bii 65 C.E.) apọsteli Pọọlu ni a fisẹwọn ni Romu lẹẹkan sii. Bi o tilẹ jẹ pe o dojukọ iku, oun nigba naa kọ lẹta rẹ keji si Timoti.

      Lẹta Pọọlu mura Timoti silẹ lati dena awọn apẹhinda ki o si duro gbọnyin ni oju inunibini. O fun un ni iṣiri lati maa baa lọ ninu nini itẹsiwaju o si sọ nipa awọn ipo Pọọlu ninu ẹ̀wọ̀n. Lẹta naa tun ran awọn onkawe lọwọ lati gbarale okun ti Ọlọrun fifunni.

      Jiya Ibi Ki O Si Kọni Pẹlu Iwatutupẹlẹ

      Ọlọrun nfi okun fun wa lati farada inunibini gẹgẹ bi olupokiki ihin rere naa. (1:1-18, NW) Pọọlu ko gbagbe Timoti lae ninu awọn adura rẹ, o si ranti igbagbọ alaini agabagebe rẹ̀. Ọlọrun fun Timoti ‘kii ṣe ẹmi ojo, bikoṣe ẹmi agbara, ifẹ, ati yiyekooro ero inu.’ Nitori naa ki oun maṣe tiju ninu jijẹrii ati jijiya ibi fun ihin rere. A tun rọ ọ lati “maa di apẹẹrẹ ọnà awọn ọ̀rọ̀ yiyekooro mu” eyi ti o gbọ lati ẹnu Pọọlu, ani gẹgẹ bi awa ti nilati rọ̀ timọtimọ laigbagbẹrẹ mọ ojulowo otitọ Kristian bi o tilẹ jẹ pe awọn miiran yipada kuro ninu rẹ̀.

      Awọn ohun ti Pọọlu fi kọni ni a nilati fi le awọn oloootọ eniyan lọwọ ti wọn yoo fi kọ awọn ẹlomiran. (2:1-26) Timoti ni a rọ̀ lati jẹ ọmọ ogun rere ti Kristi, ti o jẹ oloootọ nigba ti o ba njiya ibi. Pọọlu funraarẹ jiya ninu ide ẹwọn fun wiwaasu ihinrere. O fun Timoti ni iṣiri lati sa gbogbo ipa rẹ lati fi araarẹ han ni aṣiṣẹ tí Ọlọrun tẹwọgba, ni kikọ awọn ọ̀rọ̀ asán ti nba ohun mimọ jẹ. A sì sọ fun un pe ẹru Oluwa gbọdọ fun awọn ẹlomiran ni itọni pẹlu iwàtútùpẹ̀lẹ́.

      Waasu Ọ̀rọ̀ Naa!

      Okun ti Ọlọrun fifunni ni a o nilo lati dojukọ awọn ọjọ ikẹhin ki a sì di otitọ Iwe Mimọ mu. (3:1-17, NW) Lati inu awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ni awọn ọkunrin ti wọn nfi ‘igbagbogbo kẹkọọ sibẹ ti wọn ko lè de oju imọ pipeye otitọ lae’ yoo ti dide. ‘Iru awọn eniyan buruku ati awọn afàwọ̀rajà’ bẹẹ ‘yoo maa lọ lati buburu si buburu jáì, wọn o maa ṣinilọna a o sì maa ṣi wọn lọna.’ Bi o ti wu ki o ri, Timoti nilati ‘maa baa lọ ninu awọn ohun ti oun ti kọ.’ Bẹẹ ni awa pẹlu gbọdọ ṣe, ni mimọ pe ‘gbogbo Iwe Mimọ ni Ọlọrun mísí o sì lere fun ẹkọ, ifibawitọnisọna, mimu awọn nnkan tọ́ taarata, ati bibaniwi ninu òdodo, ki eniyan Ọlọrun le yẹ ni kikun, ti a ti mu gbaradi patapata fun iṣẹ daradara gbogbo.’

      Timoti nilati dena awọn apẹhinda ki o si ṣaṣepari iṣẹ ojiṣẹ rẹ. (4:1-22) Oun le ṣe bẹẹ nipa ‘wiwaasu ọrọ naa’ ki o si tẹramọ ṣiṣe e. Eyi ṣe pataki, niwọnbi ijọ naa ti dojukọ “asiko ijangbọn” nitori pe awọn kan nkọni ni ẹkọ igbagbọ eke. Awọn Ẹlẹrii Jehofa tun rọ̀mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nisinsinyi, ni wiwaasu rẹ ní kanjukanju ninu ijọ ati fun awọn eniyan lẹhin ode, ani ni awọn ipo ti ko rọgbọ paapaa. Pọọlu “pa igbagbọ mọ,” bi o tilẹ jẹ pe awọn kan ti kọ̀ ọ́ ti. Ṣugbọn ‘Oluwa fi agbara fun un, pe nipasẹ rẹ ki a le ṣe aṣepari iwaasu naa ni kikun.’ Njẹ ki awa pẹlu gbarale okun ti Ọlọrun fifunni ki a si maa baa niṣo ni wiwaasu ihin rere naa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́