Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akéde Tó Bá Lọ sí Ìjọ Míì Lọ́wọ́
1. (a) Bí akéde kan bá lọ sí ìjọ míì, kí ló yẹ kí akọ̀wé ìjọ tó wà tẹ́lẹ̀ àti akọ̀wé ìjọ tuntun náà ṣe? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n bójú tó lẹ́tà ìfinimọni? (d) Ìgbà wo ló máa pọn dandan pé kí wọ́n fi káàdì (tàbí, àwọn káàdì) ẹnì kan ránṣẹ́ sí ìjọ tá á máa dara pọ̀ mọ́?
1 Láwọn ìgbà míì, ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé kí akéde kan ti ibì kan lọ sí ibòmíràn. Kí ohunkóhun má bàa yingin lára ìjọsìn irú akéde bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ tètè bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó bá wà nítòsí ibi tó lọ, kó má sì jáfara láti jẹ́ káwọn alàgbà mọ̀ ọ́n. (Òwe 18:1) Bó bá máa lò ju oṣù mẹ́ta lọ níbẹ̀, kó sọ àdírẹ́sì ìjọ tó wà tẹ́lẹ̀ fún akọ̀wé ìjọ tuntun náà, kó bàa lè tètè béèrè fún káàdì (tàbí, àwọn káàdì) rẹ̀, ìyẹn Congregation’s Publisher Record àti lẹ́tà ìfinimọni tí ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn buwọ́ lù. Bó bá sì mọ orúkọ àti àdírẹ́sì ìjọ tá á máa dara pọ̀ mọ́ níbi tó ń lọ, kó fún akọ̀wé ìjọ ní irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ kó tó lọ. Bó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa retí pé kí ìjọ tá á máa dara pọ̀ mọ́ níbi tó ń lọ ṣẹ̀ṣẹ̀ béèrè fún káàdì rẹ̀ kí wọ́n tó fi ránṣẹ́.—Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 88.
2. Kí ni akọ̀wé gbọ́dọ̀ ṣe kó lè rí i dájú pé wọ́n rí káàdì àti lẹ́tà ìfinimọni akéde gbà ní ìjọ tó fi ránṣẹ́ sí?
2 Tí ibi tó lọ bá jìnnà, kí wọ́n tipasẹ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì fi káàdì (tàbí, àwọn káàdì) náà ránṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀ tuntun. Lọ́nà yìí, káàdì náà ò ní sọ nù. Bí ìjọ tuntun náà ò bá jìnnà, àwọn alàgbà lè mú lẹ́tà náà lọ síbẹ̀. Kí akọ̀wé ìjọ tó wà tẹ́lẹ̀ tọ́jú ẹ̀dà káàdì (tàbí, àwọn káàdì) náà àti ẹ̀dà lẹ́tà ìfinimọni, títí tó fi máa rí i dájú pé ìjọ tuntun náà rí èyí tó fi ránṣẹ́ gbà.
3. Báwo ló ṣe yẹ kí akọ̀wé bójú tó àwọn ìròyìn akéde tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé ìjọ wọn, kí ló sì gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tó bá rí káàdì rẹ̀ gbà?
3 Bí wọn ò bá tètè rí káàdì náà gbà, kí akọ̀wé ìjọ tuntun náà má ṣe ṣí káàdì kankan fún akéde náà, àmọ́ kó máa tọ́jú gbogbo ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá tí akéde náà bá fún un, títí tí káàdì rẹ̀ á fi dé. Lẹ́yìn tí akọ̀wé bá ti rí káàdì akéde náà gbà, kó kọ àwọn ìròyìn tí akéde náà ti fún un sínú rẹ̀, kó sì fi àròpọ̀ wọn kún ìròyìn tí ìjọ máa fi ránṣẹ́ lóṣù yẹn, ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni tá a ti fi ránṣẹ́ nípa bó ṣe yẹ kí akọ̀wé máa bójú tó àwọn ìròyìn tó bá pẹ́.
4. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè ran àwọn akéde tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ míì lọ́wọ́?
4 Kí gbogbo alàgbà, òbí tàbí alágbàtọ́, àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni pawọ́ pọ̀ láti máa rán akéde tó bá lọ síbòmíràn létí ohun tó gbọ́dọ̀ ṣe kó bàa lè máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà níbẹ̀ déédéé. Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ tá á máa dara pọ̀ mọ́, àti pàápàá jù lọ àwọn alàgbà, gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀ràn irú akéde bẹ́ẹ̀ jẹ àwọn lógún, kí wọ́n má fàkókò falẹ̀ láti mọbi tí wọ́n ń gbé kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ títí tí ara wọn á fi mọlé.—Róòmù 15:7; 2 Kọ́r. 6:11-13.