-
Eeṣe Ti A Fi Nilati Gbé Irẹlẹ Wọ̀?Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | July 15
-
-
tẹle awọn onirẹlẹ.” (Roomu 12:16) Bi o ti wu ki o ri, bawo ni irẹlẹ ṣe le ṣanfaani fun wa ati awọn ẹlomiran?
Awọn Anfaani Irẹlẹ
Anfaani irẹlẹ kan ni pe o ká wa lọwọ ko kuro ninu fífọ́nnu nipa ara wa. A tipa bayii dá awọn ẹlomiran sí lọwọ ibinu a o si yẹra fun kiko ojuti ba ara wa bi awọn aṣeyọri wa ko ba fà wọn mọra. A nilati yangàn ninu Jehofa, kii ṣe ninu araawa.—1 Kọrinti 1:31.
Irẹlẹ nran wa lọwọ lati gba idari atọrunwa. Jehofa ran angẹli kan si Daniẹli pẹlu iran kan nitori pe wolii yẹn rẹ araarẹ silẹ niwaju Ọlọrun nigba ti o nwa itọsọna ati oye kiri. (Daniẹli 10:12) Nigba ti o fẹrẹẹ tó akoko fun Ẹsira lati ṣamọna awọn eniyan Jehofa jade kuro ni Babiloni pẹlu ọpọlọpọ wura ati fadaka fun mimu tẹmpili ni Jerusalẹmu lẹwa, oun kede aawẹ ki wọn baa le rẹ araawọn silẹ niwaju Ọlọrun. Ki ni iyọrisi rẹ? Jehofa daabobo wọn kuro lọwọ ikọluni ọta lakooko irin ajo elewu naa. (Ẹsira 8:1-14, 21-32) Bii Daniẹli ati Ẹsira, ẹ jẹ ki a fi irẹlẹ han ki a si wa itọsọna Jehofa dipo gbigbiyanju lati mu awọn iṣẹ ti Ọlọrun yan fun wa ṣẹ nipa ọgbọn ati agbara tiwa funraawa.
Bi a ba gbe ẹwu irẹlẹ wọ̀, awa yoo bọwọ fun awọn ẹlomiran. Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ ti wọn ni irẹlẹ maa nbọwọ fun wọn si maa nṣegbọran si awọn obi wọn. Awọn Kristẹni onirẹlẹ tun nbọwọ fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn jẹ ti orilẹ-ede, ẹya, ati ipilẹ igbesi-aye miiran, nitori irẹlẹ mu wa jẹ alaiṣojuṣaaju.—Iṣe 10:34, 35; 17:26.
Irẹlẹ maa ngbe ifẹ ati alaafia ga. Onirẹlẹ kan kii ba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ jà ninu isapa lati fidi awọn ẹtọ ti o lero pe oun ni mulẹ. Pọọlu ṣe kiki awọn ohun ti ngbeniro ki yoo si daamu ẹri-ọkan arakunrin kankan. (Roomu 14:19-21; 1 Kọrinti 8:9-13; 10:23-33) Irẹlẹ tun nran wa lọwọ lati gbe ifẹ ati alaafia ga nipa didari ji awọn ẹlomiran fun awọn ẹṣẹ wọn lodisi wa. (Matiu 6:12-15; 18:21, 22) O nsun wa lati lọ sọdọ ẹni a ṣẹ̀, ki a gba aṣiṣe wa, beere fun idariji rẹ, ki a si ṣe ohun ti a le ṣe lati ṣatunṣe aṣiṣe eyikeyii ti a ti le ṣe. (Matiu 5:23, 24; Luuku 19:8) Bi ẹni kan ti a ṣẹ̀ ba wa sọdọ wa, irẹlẹ nsun wa lati yanju awọn ọran pẹlu alaafia ninu ẹmi ifẹ.—Matiu 18:15; Luuku 17:3.
Igbala sinmi lori fifi ẹmi irẹlẹ han. Fun apẹẹrẹ, nipa Ọlọrun, a sọ pe: “Awọn eniyan onirẹlẹ ni iwọ yoo gbala; ṣugbọn oju rẹ lodisi awọn agberaga, ki iwọ le rẹ̀ wọn walẹ.” (2 Samuẹli 22:28, NW) Nigba ti Ọba Jesu Kristi ba ‘gẹṣin ninu ipa otitọ, irẹlẹ, ati ododo,’ oun yoo gba awọn wọnni ti wọn rẹ araawọn silẹ niwaju rẹ ati Baba rẹ là. (Saamu 45:4) Awọn wọnni ti wọn fi irẹlẹ han le ri itunu ninu awọn ọrọ naa pe: “Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW], gbogbo ẹyin ọlọkan tutu aye, ti nṣe idajọ rẹ; ẹ wa ododo, ẹ wa iwa pẹlẹ: boya a o pa yin mọ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Sefanaya 2:3.
Irẹlẹ ati Eto-ajọ Ọlọrun
Irẹlẹ maa nṣamọna awọn eniyan Ọlọrun lati mọriri eto-ajọ rẹ ki wọn si duro tì í gẹgẹ bi awọn olupa iwa titọ mọ́. (Fiwe Johanu 6:66-69.) Bi a ko ba ri anfaani iṣẹ-isin ti a nreti gbà, irẹlẹ yoo ran wa lọwọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn wọnni ti wọn ni ẹru-iṣẹ ninu ijọ. Ifọwọsowọpọ onirẹlẹ wa si fi apẹẹrẹ rere lelẹ.
Ni ọwọ keji ẹwẹ, ẹmi irẹlẹ pa wa mọ kuro ninu fifi ọkan giga han jade ni isopọ pẹlu awọn anfaani iṣẹ-isin wa laaarin awọn eniyan Jehofa. O ká wa lọwọ kò kuro ninu wiwa iyin fun iṣẹ ti a ni anfaani lati ṣe ninu eto-ajọ Ọlọrun. Ju bẹẹ lọ, bi a ba ni anfaani lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba, irẹlẹ ran wa lọwọ lati huwa si agbo Ọlọrun lọna jẹlẹnkẹ.—Iṣe 20:28, 29; 1 Peteru 3:8.
Irẹlẹ ati Ibawi
Ẹwu irẹlẹ nran wa lọwọ lati tẹwọgba ibawi. Awọn eniyan onirẹlẹ ko dabii Usaya Ọba Juda, ẹni ti ọkan-aya rẹ gberaga gan an tobẹẹ debi pe o fipa gba iṣẹ alufaa ṣe. O ‘huwa lọna aiṣododo lodi si Jehofa o si wá sinu tẹmpili lati fi turari jona lori pẹpẹ turari.’ Nigba ti Usaya binu si awọn alufaa fun titọ ọ sọna, a fi ẹtẹ kọlu u. Ẹ wo iye ti o san fun aini irẹlẹ! (2 Kironika 26:16-21; Owe 16:18) Maṣe dabi Usaya lae ki o si jẹki igberaga ṣèdènà rẹ lati gba ibawi lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Ọrọ ati eto-ajọ Rẹ.
Nipa eyi Pọọlu sọ fun awọn Kristẹni Heberu ẹni ami ororo pe: “Ẹyin si ti gbagbe ọrọ iyanju ti nba yin sọ bi ọmọ pe, ọmọ mi, maṣe alaini ibawi Oluwa [“Jehofa,” NW], ki o ma si ṣe rẹwẹsi nigba ti a ba nti ọwọ rẹ̀ ba ọ wi: nitori pe ẹni ti Oluwa fẹ, oun ni iba wi, a si maa na olukuluku ọmọ ti o gba . . . Gbogbo ibawi ko dabi ohun ayọ nisinsinyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alaafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ, ani eso ododo.” (Heberu 12:5-11) Ranti pẹlu, pe “ibawi ẹkọ ni ọna iye.”—Owe 6:23.
Ẹ Wà Ni Ẹni Ti O Gbe Irẹlẹ Wọ̀
Bawo ni o ti ṣe pataki tó pe ki awọn Kristẹni maa wọ ẹwu irẹlẹ nigba gbogbo! O sun wa lati foriti gẹgẹ bi awọn olupokiki Ijọba, ni jijẹrii pẹlu irẹlẹ lati ile de ile ni wiwa awọn wọnni “ti wọn ni itẹsi ọkan lọna titọ fun iye ainipẹkun kiri.” (Iṣe 13:48, NW; 20:20) Nitootọ, irẹlẹ nran wa lọwọ lati maa baa lọ ni ṣiṣegbọran si Ọlọrun ni gbogbo ọna, bi o tilẹ jẹ pe awọn aṣodi onigberaga koriira ipa ọna ododo wa.—Saamu 34:21.
Nitori pe irẹlẹ sun wa lati ‘nigbẹẹkẹle ninu Jehofa pẹlu gbogbo ọkan-aya wa,’ oun mu ki ipa ọna wa tọ́. (Owe 3:5, 6) Niti tootọ, ayafi bi a ba gbé animọ rere yii wọ̀ ni a to le rin pẹlu Ọlọrun ki a si gbadun ifọwọsi ati ibukun rẹ nitootọ. Gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin naa Jakọbu ti kọwe: “Ẹ rẹ ara yin silẹ niwaju Oluwa [“Jehofa,” NW], oun o si gbe yin ga.” (Jakọbu 4:10) Nitori naa ẹ jẹ ki a gbe irẹlẹ wọ̀, ẹwu meremere yẹn ti Jehofa Ọlọrun ṣẹda rẹ.
-
-
Ipade Ọdọọdun—October 5, 1991Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | July 15
-
-
Ipade Ọdọọdun—October 5, 1991
IPADE ỌDỌỌDUN ti mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 5, 1991, ni Gbọngan Apejọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kiki awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ ni 9:30 a.m., ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo si tẹle e ni 10:00 a.m.
Awọn mẹmba Ajọ-ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyi ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ti ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ati iwe aṣẹ ìṣojúfúnni lè dé ọdọ wọn kété lẹhin August 1.
Awọn iwe aṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o firanṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitóniléti nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki o ba le dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọrọ kun iwe aṣẹ ìsọfúnni tirẹ kíámọ́sá ki o sì dá a pada ki o sọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa funraarẹ tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe aṣẹ ìsojúfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale eyi ni pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ funraawọn.
A fojusọna pe gbogbo akoko ijokoo naa, titi kan awọn ipade iṣẹ àmójútó eleto aṣa ati awọn irohin, ni a o pari rẹ ni 1:00 p.m. tabi kété lẹhin naa. Ki yoo si akoko ijokoo ọsan. Nitori aye ti o mọniwọn, igbawọle yoo jẹ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoso. Ko si iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ mọ waya tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.
-