-
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 8
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?
Orílẹ̀-èdè Iceland
Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò
Orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau
Orílẹ̀-èdè Philippines
Ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àwòrán inú ìwé yìí bí wọ́n ṣe múra dáadáa nígbà tí wọ́n ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ? Kí nìdí tí a fi máa ń rí i pé aṣọ àti ìmúra wa bójú mu?
Ká lè bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run wa. Òótọ́ ni pé ìrísí wa nìkan kọ́ ni Ọlọ́run ń wò, ó tún má ń wo inú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nígbà tí a bá pé jọ láti sin Ọlọ́run, ohun tá a fẹ́ látọkàn wá ni pé ká bọ̀wọ̀ fún un àti fún àwọn tá a jọ ń sìn ín. Tá a bá fẹ́ lọ síwájú ọba tàbí ààrẹ orílẹ̀-èdè, a máa múra dáadáa torí pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n. Bákan náà, bí a ṣe múra wá sí ìpàdé ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé” àti fún ibi tá a ti ń jọ́sìn rẹ̀.—1 Tímótì 1:17.
Ká lè fi ìlànà tí à ń tẹ̀ lé hàn. Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé ká máa múra lọ́nà tó fi “ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀” hàn. (1 Tímótì 2:9, 10) Ìmúra tó fi “ìmọ̀wọ̀n ara ẹni” hàn túmọ̀ sí pé ká má ṣe wọ aṣọ tó máa mú káwọn èèyàn máa wò wá, ìyẹn kéèyàn máa wọṣọ torí kó lè ṣe fọ́rífọ́rí, aṣọ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀. Bákan náà, “àròjinlẹ̀” ń jẹ́ ká yan aṣọ tó dáa, ká sì yẹra fún wíwọ aṣọ jákujàku tàbí ṣíṣe àṣejù nínú ìmúra wa. Ìlànà yìí fún wa láyè kí kálukú wọ aṣọ tó wù ú tó bá ṣáà ti dáa. Bí a ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀, tí ìmúra wa bá bójú mu tó sì buyì kún wa, ó máa ‘ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́,’ á sì “yin Ọlọ́run lógo.” (Títù 2:10; 1 Pétérù 2:12) Tá a bá múra dáadáa lọ sí àwọn ìpàdé wa, ó máa mú káwọn èèyàn fojú tó dáa wo ìjọsìn Jèhófà.
Má ṣe kọ ìpàdé sílẹ̀ torí pé o kò ní irú aṣọ kan tó o máa wọ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò dìgbà tí aṣọ wa bá jẹ́ olówó ńlá tàbí tó rí rèǹtè-rente kó tó jẹ́ aṣọ tó dáa, tó mọ́ tónítóní, tó sì bójú mu.
Kí nìdí tí ìmúra wa fi ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run?
Àwọn ìlànà wo la máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra?
-
-
Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 9
Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?
Orílẹ̀-èdè Kàǹbódíà
Orílẹ̀-èdè Ukraine
Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó o máa múra ibi tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ kẹ́ ẹ tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bákan náà, ó dára kó o máa múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀ kó o tó lọ, kó o lè jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. Téèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, ẹ̀kọ́ púpọ̀ lá máa rí kọ́.
Pinnu ìgbà tó o máa múra ìpàdé àti ibi tó o ti máa múra. Ìgbà wo ló rọrùn fún ẹ jù láti pọkàn pọ̀? Ṣé àárọ̀ kùtù ni, kó o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àbí lálẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ti lọ sùn? Ká tiẹ̀ sọ pé o ò lè fi àkókò gígùn kẹ́kọ̀ọ́, yan iye àkókò tó o lè lò, kó o sì rí i dájú pé ohunkóhun ò dí ẹ lọ́wọ́. Wá ibi tí kò sí ariwo, kó o sì yẹra fún gbogbo ohun tó lè gbà ẹ́ lọ́kàn, pa rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti fóònù rẹ. Máa gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ kó o lè kó àníyàn ọjọ́ yẹn kúrò lọ́kàn kó o sì pọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Fílípì 4:6, 7.
Sàmì sí àwọn kókó inú ibi tí a fẹ́ kọ́, kó o sì múra láti dá sí i. Kọ́kọ́ wo àwọn kókó tó wà nínú ibi tá a fẹ́ kọ́. Ronú nípa àkòrí àpilẹ̀kọ tàbí orí ìwé náà, kó o sì wo bí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ kókó pàtàkì inú àpilẹ̀kọ náà, wo àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀, kó o sì ka àwọn ìbéèrè tó gbé àwọn kókó inú ẹ̀kọ́ náà yọ. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, kà wọ́n, kó o sì ronú nípa bí wọ́n ṣe ti ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn. (Ìṣe 17:11) Tó o bá ti rí ìdáhùn, fa ìlà sí i tàbí kó o sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tàbí àpólà ọ̀rọ̀ nínú ìpínrọ̀ náà, tó máa jẹ́ kó o rántí ìdáhùn náà. Ní ìpàdé, o lè nawọ́ nígbà tó o bá fẹ́, kó o sì dáhùn ṣókí ní ọ̀rọ̀ ara rẹ.
Bó o ṣe ń ka oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ tá à ń jíròrò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nípàdé, wàá máa fi àwọn ohun tuntun kún ‘ibi tí ò ń kó ìṣúra sí,’ ìyẹn ìmọ̀ tó o ní nípa Bíbélì.—Mátíù 13:51, 52.
Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ déédéé?
Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ láti dáhùn ní ìpàdé?
-
-
Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 10
Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?
Orílẹ̀-èdè South Korea
Orílẹ̀-èdè Brazil
Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà
Orílẹ̀-èdè Guinea
Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti fẹ́ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí wọ́n á jọ wà pa pọ̀, kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ òun kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Diutarónómì 6:6, 7) Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń ní àkókò kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí ìdílé á fi jọ́sìn pa pọ̀, tí wọ́n á jókòó pẹ̀sẹ̀, tí wọ́n á sì jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Kódà tó bá jẹ́ pé ṣe lò ń dá gbé, ó máa dáa gan-an kó o lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, kó o fi kẹ́kọ̀ọ́ kókó kan tó wù ẹ́ nínú Bíbélì.
Ó jẹ́ àkókò láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) A máa túbọ̀ mọ Jèhófà nígbà tí a bá mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tó jẹ́ àti ìwà rẹ̀ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀nà kan tó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn ìdílé rẹ ni pé kí ẹ ka Bíbélì sókè. Ẹ lè máa tẹ̀ lé ètò Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ lè yan apá kan nínú Bíbélì náà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láti kà, kí gbogbo yín sì jíròrò ohun tí ẹ kọ́ níbẹ̀.
Ó jẹ́ àkókò tí ìdílé túbọ̀ máa ń wà níṣọ̀kan. Àwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ túbọ̀ máa ń wà níṣọ̀kan tí wọ́n bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ nínú ìdílé. Ó yẹ kó jẹ́ àkókò ayọ̀ àti àlàáfíà, kó sì tún jẹ́ ohun tí wọ́n á máa wọ̀nà fún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn òbí lè yan ohun tí wọ́n á jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí ọjọ́ orí àwọn ọmọ wọn bá ṣe mọ, wọ́n lè yan àkòrí kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí látorí ìkànnì jw.org/yo. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tí àwọn ọmọ yín ní nílé ìwé àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ̀. Ẹ lè wò lára àwọn ètò wa lórí Tẹlifíṣọ̀n JW (tv.jw.org) kẹ́ ẹ sì jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ tún lè fi àwọn orin tí a máa kọ ní ìpàdé dánra wò, kẹ́ ẹ sì gbádùn rẹ̀. Ẹ sì lè jẹ ìpápánu lẹ́yìn ìjọsìn ìdílé yín.
Àkókò pàtàkì tí ẹ̀ ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ yìí máa ran gbogbo yín lọ́wọ́ kí ẹ lè jadùn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run á sì mú kí ìsapá yín yọrí sí rere.—Sáàmù 1:1-3.
Kí nìdí tá a fi ní àkókò tá a máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé?
Báwo ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí gbogbo ìdílé gbádùn ìjọsìn ìdílé?
-