-
Kí Nìdí Tí A Fi Ń Lọ sí Àwọn Àpéjọ Ńlá?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 11
Kí Nìdí Tí A Fi Ń Lọ sí Àwọn Àpéjọ Ńlá?
Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò
Orílẹ̀-èdè Jámánì
Orílẹ̀-èdè Botswana
Orílẹ̀-èdè Nicaragua
Orílẹ̀-èdè Ítálì
Kí nìdí tínú àwọn èèyàn yìí fi ń dùn? Torí pé wọ́n wà ní ọ̀kan lára àwọn àpéjọ wa ni. Bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́, tí Ọlọ́run sọ fún pé kí wọ́n máa pé jọ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún, àwa náà máa ń fojú sọ́nà fún àwọn ìgbà tá a máa ń lọ sí àpéjọ ńlá. (Diutarónómì 16:16) Àpéjọ mẹ́ta la máa ń ṣe lọ́dọọdún, àwọn ni: àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ kan, tó máa ń wáyé lẹ́ẹ̀méjì àti àpéjọ agbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Báwo ni àwọn àpéjọ yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
Wọ́n ń mú kí ẹgbẹ́ ará wa túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń yin Jèhófà ní “àwọn àpéjọ,” bẹ́ẹ̀ náà ni inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ń jọ́sìn rẹ̀ láwọn àpéjọ pàtàkì. (Sáàmù 26:12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; 111:1) Àwọn àpéjọ yìí máa ń jẹ́ ká lè pàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti àwọn ìjọ míì tàbí àwọn orílẹ̀-èdè míì pàápàá, ká sì jọ fara rora. Ní ọ̀sán, a máa ń jẹun pa pọ̀ ní gbọ̀ngàn àpéjọ wa, èyí sì ń jẹ́ ká túbọ̀ gbádùn àjọṣe alárinrin láwọn àpéjọ náà. (Ìṣe 2:42) Láwọn àpéjọ yìí, a máa ń fojú ara wa rí ìfẹ́ tó so “gbogbo àwọn ará” wa pọ̀ kárí ayé.—1 Pétérù 2:17.
Wọ́n ń mú ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jàǹfààní torí pé ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ṣàlàyé fún wọn “yé wọn.” (Nehemáyà 8:8, 12) Àwa náà mọyì ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a máa ń kọ́ láwọn àpéjọ wa. Inú Bíbélì la ti mú àwọn ẹ̀kọ́ náà. À ń kọ́ bá a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láyé wa látinú àwọn àsọyé alárinrin, àpínsọ àsọyé àtàwọn àṣefihàn ohun tó ṣẹlẹ̀. Tá a bá gbọ́ bí àwọn ará wa ṣe ń fara da ìṣòro tó ń dé bá àwọn Kristẹni tòótọ́ lásìkò tí nǹkan nira yìí, ó máa ń fún wa ní ìṣírí. Ní àwọn àpéjọ agbègbè wa, àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kí àwọn ìtàn inú Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere, wọ́n sì ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò. Ní gbogbo àpéjọ, a máa ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn tó fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Kí nìdí tí àwọn àpéjọ wa fi máa ń fún wa láyọ̀?
Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá wá sí àpéjọ wa?
-
-
Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 12
Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?
Orílẹ̀-èdè Sípéènì
Orílẹ̀-èdè Belarus
Orílẹ̀-èdè Hong Kong
Orílẹ̀-èdè Peru
Ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mátíù 24:14) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó máa kárí ayé yìí? Bí a ṣe máa ṣe é ni pé, a máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó wà láyé.—Lúùkù 8:1.
À ń wá àwọn èèyàn lọ sílé wọn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé. (Mátíù 10:11-13; Ìṣe 5:42; 20:20) Àwọn ajíhìnrere ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń wàásù. (Mátíù 10:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 10:13) Bákan náà lónìí, a ṣètò iṣẹ́ ìwàásù wa dáadáa, a sì fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ibi tí wọ́n á ti máa wàásù. Èyí jẹ́ ká lè máa tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa fún wa pé ká “wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná.”—Ìṣe 10:42.
À ń sapá láti wàásù fún àwọn èèyàn láwọn ibi tá a ti lè rí wọn. Jésù tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ bó ṣe wàásù níbi táwọn èèyàn máa ń wà, irú bí etíkun tàbí nídìí kànga àdúgbò. (Máàkù 4:1; Jòhánù 4:5-15) Àwa náà máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì láwọn ibi tá a ti lè ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, níbi iṣẹ́, nínú ọgbà ìgbafẹ́ tàbí lórí fóònù. A tún máa ń wàásù fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa nígbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Gbogbo àwọn ohun tí à ń ṣe yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé gbọ́ “ìhìn rere ìgbàlà.”—Sáàmù 96:2.
Ta lo rò pé o lè sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àti ohun tí ìyẹn máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú? Má ṣe fi ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí mọ sọ́dọ̀ ara rẹ nìkan. Sọ ọ́ fún wọn láìjáfara!
“Ìhìn rere” wo la gbọ́dọ̀ kéde?
Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
-
-
Àwọn Wo Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 13
Àwọn Wo Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?
Orílẹ̀-èdè Kánádà
Ìwàásù ilé-dé-ilé
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Ìdákẹ́kọ̀ọ́
Ọ̀rọ̀ náà “aṣáájú-ọ̀nà” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tó lọ wá agbègbè tuntun, tí wọ́n sì la ọ̀nà fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn. A lè pe Jésù ní aṣáájú-ọ̀nà torí Ọlọ́run rán an wá sí ayé kó wá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fúnni ní ìyè, kó sì ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún àwa èèyàn. (Mátíù 20:28) Lónìí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn kan lára wọn ń ṣe iṣẹ́ tí à ń pè ní iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kéde ìhìn rere. Àmọ́, àwọn kan ti ṣètò ìgbé ayé wọn kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n máa ń fi àádọ́rin (70) wákàtí wàásù lóṣooṣù. Ọ̀pọ̀ wọn ti dín àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kù kí wọ́n lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. A ti yan àwọn kan láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i, wọ́n sì ń fi àádóje (130) wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wàásù lóṣooṣù. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tó pọn dandan fún wọn. (Mátíù 6:31-33; 1 Tímótì 6:6-8) Àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti àkànṣe lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn ìgbà tó bá ṣeé ṣe, wọ́n á lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó lè jẹ́ ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí lóṣù.
Ìfẹ́ tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ náà. Bíi ti Jésù, a kíyè sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe. (Máàkù 6:34) A mọ ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ báyìí, tó máa mú kí wọ́n ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ìfẹ́ tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà ní sí àwọn èèyàn ló ń mú kí wọ́n máa lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun wọn láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run. (Mátíù 22:39; 1 Tẹsalóníkà 2:8) Ìyẹn ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà lágbára, kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa láyọ̀ gan-an.—Ìṣe 20:35.
Àwọn wo là ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà?
Kí ló mú kí àwọn kan máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé tàbí àkànṣe?
-