ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 17

      Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

      Alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀

      Orílẹ̀-èdè Màláwì

      Alábòójútó àyíká ń darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá

      Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù

      Alábòójútó àyíká ń wàásù

      Wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

      Alábòójútó àyíká ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà

      Ìpàdé àwọn alàgbà

      Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ wò nígbà yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn ará tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ “pa dà lọ bẹ àwọn ará wò” kí òun lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Ó múra tán láti rin ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kó lè lọ fún wọn ní ìṣírí. (Ìṣe 15:36) Ohun kan náà tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wa ń ṣe lónìí nìyẹn.

      Wọ́n ń bẹ̀ wá wò kí wọ́n lè fún wa níṣìírí. Alábòójútó àyíká máa ń bẹ nǹkan bí ogún (20) ìjọ wò, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan ní ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú ìrírí àwọn arákùnrin yìí àti ti ìyàwó wọn, tí wọ́n bá ní ìyàwó. Wọ́n máa ń sapá láti mọ tèwe tàgbà, a jọ máa ń lọ wàásù, a sì jọ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alábòójútó yìí àtàwọn alàgbà jọ máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó ń gbéni ró láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.​—Ìṣe 15:35.

      Wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń wá bí ìjọ ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ń ṣe dáadáa sí, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí, wọ́n tún máa ń fẹ́ mọ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ló ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, “a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire [wa].” (2 Kọ́ríńtì 8:23) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run.​—Hébérù 13:7.

      • Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò?

      • Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Lórí kàlẹ́ńdà rẹ, sàmì sí ìgbà tí alábòójútó àyíká tún máa bẹ ìjọ yín wò kí ohunkóhun má bàa dí ẹ lọ́wọ́ láti wá gbọ́ àwọn àsọyé tó máa sọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kó o bàa lè mọ alábòójútó àyíká tàbí ìyàwó rẹ̀ dáadáa, sọ fún ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé o fẹ́ kí ọ̀kan lára wọn wà níbẹ̀ nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò yẹn.

  • Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 18

      Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic

      Orílẹ̀-èdè Dominican Republic

      Àwọn tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ ní orílẹ̀-èdè Japan

      Orílẹ̀-èdè Japan

      Ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tu ẹnì kan nínú nígbà àjálù tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti

      Orílẹ̀-èdè Haiti

      Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò ìrànwọ́ tó máa mú kí ara tu àwọn ará wa tí àjálù bá. Irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ ló wà láàárín wa. (Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:17, 18) Àwọn ìrànlọ́wọ́ wo la máa ń ṣe?

      A máa ń fowó ṣèrànwọ́. Nígbà tí ìyàn ńlá mú ní Jùdíà, àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni ní ìlú Áńtíókù fi owó ránṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọn ní Jùdíà. (Ìṣe 11:27-30) Lọ́nà kan náà, tá a bá gbọ́ pé nǹkan nira fún àwọn ará wa láwọn apá ibì kan láyé, a máa ń fi owó ṣètìlẹyìn láwọn ìjọ wa, kí wọ́n lè fi pèsè àwọn nǹkan tí àwọn ará náà nílò lásìkò tí nǹkan nira fún wọn.​—2 Kọ́ríńtì 8:13-15.

      A máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Àwọn alàgbà tó bá wà níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ máa ń wá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ kàn, láti rí i pé gbogbo wọn wà lálàáfíà. Ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ máa ń ṣètò oúnjẹ, omi tó mọ́, aṣọ, ilé gbígbé, wọ́n sì ń bójú tó ìlera àwọn tọ́rọ̀ kàn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mọ iṣẹ́ tí wọ́n lè fi ṣàtúnṣe ibi tí àjálù bà jẹ́, máa ń ná owó ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá tàbí kí wọ́n lọ tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe. Bá a ṣe wà níṣọ̀kan nínú ètò wa àti ìrírí tá a ti ní bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ máa ń jẹ́ ká lè tètè kóra jọ láti ṣèrànwọ́ nígbà ìṣòro. Bí a ṣe ń ṣèrànwọ́ fún “àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” la tún ń ṣèrànwọ́ fún àwọn míì tó bá ṣeé ṣe, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí.​—Gálátíà 6:10.

      A máa ń fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn èèyàn nínú. Àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí máa ń nílò ìtùnú gan-an. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, a máa ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Inú wa máa ń dùn láti sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tí ìdààmú bá, à ń mú un dá wọn lójú pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àjálù tó ń fa ìrora àti ìjìyà bá aráyé.​—Ìfihàn 21:4.

      • Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa tètè ṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?

      • Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè fi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó yè bọ́ nínú àjálù?

  • Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 19

      Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

      Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀
      Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì

      Gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí

      Méjì lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

      Nígbà tí ikú Jésù ti sún mọ́lé gan-an, ó bá mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ìyẹn Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti Áńdérù. Bó ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì tó máa fi hàn pé òun ti wà níhìn-ín ní ọjọ́ ìkẹyìn, ó béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pé: “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?” (Mátíù 24:​3, 45; Máàkù 13:​3, 4) Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun tí òun jẹ́ “ọ̀gá” wọn, máa yan àwọn táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àkókò òpin. Àwọn wo ló máa para pọ̀ jẹ́ ẹrú náà?

      Ó jẹ́ àwùjọ kékeré lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. “Ẹrú” náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. A gbára lé ẹrú olóòótọ́ yìí láti máa fún wa ní “ìwọ̀n oúnjẹ” wa “ní àkókò tó yẹ.”​—Lúùkù 12:42.

      Ó ń bójú tó agbo ilé Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:15) Jésù gbé iṣẹ́ ńlá fún ẹrú náà láti máa bójú tó iṣẹ́ tó jẹ́ ti apá orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, ìyẹn bíbójútó àwọn ohun ìní rẹ̀, dídarí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ wa nípasẹ̀ ìjọ. Nítorí náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè ohun tá a nílò fún wa ní àkókò tó yẹ, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìwé tí à ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nípasẹ̀ àwọn ohun tí à ń kọ́ ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.

      Ẹrú náà jẹ́ olóòótọ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni àti iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Bíbélì pa láṣẹ, ó sì jẹ́ olóye torí pé ó ń fi ọgbọ́n bójú tó àwọn ohun ìní Kristi láyé. (Ìṣe 10:42) Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ẹrú náà, ó ń jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí wọ́n ní oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ gan-an.​—Àìsáyà 60:22; 65:13.

      • Ta ni Jésù yàn pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

      • Kí ni ẹrú náà ń ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́ àti olóye?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́