ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 20

      Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?

      Ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní

      Ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní

      Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń ka lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ sí ìjọ

      Wọ́n ń ka lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ

      Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwùjọ kékeré kan, ìyẹn “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù,” ló jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Ìṣe 15:2) Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa ń jíròrò àti bí wọ́n ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wọn, ló ń mú kí wọ́n lè máa fohùn ṣọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu. (Ìṣe 15:25) Àpẹẹrẹ yẹn là ń tẹ̀ lé lóde òní.

      Ọlọ́run ń lo ìgbìmọ̀ náà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, àwọn arákùnrin yìí sì ní ìrírí tó pọ̀ nínú bá a ṣe ń bójú tó àwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àti ìjọsìn wa. Wọ́n máa ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nílò. Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, à ń rí àwọn ìtọ́ni tá a gbé ka Bíbélì gbà nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí nípasẹ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn míì. Èyí ń jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa ṣe ohun kan náà. (Ìṣe 16:4, 5) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó bá a ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, wọ́n ń rọ àwọn ará láti fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń bójú tó bá a ṣe ń yan àwọn arákùnrin sípò.

      Ìgbìmọ̀ náà ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun. Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbára lé Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ, ó sì ń tẹ̀ lé bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọ sọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí kì í wo ara wọn bí aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àti gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] lọ síbikíbi tó bá ń lọ.” (Ìfihàn 14:4) Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọyì àdúrà tí à ń gbà nítorí wọn.

      • Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

      • Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run lóde òní?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Ka Ìṣe 15:1-35, kó o rí bí ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe lo Ìwé Mímọ́ láti jíròrò ọ̀rọ̀ kan àti bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.

  • Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 21

      Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?

      Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì yìí ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán ní Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

      Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

      Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì

      Orílẹ̀-èdè Jámánì

      Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi ìfọṣọ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà

      Orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà

      Àwọn arákùnrin yìí ń tó àwo ìjẹun sórí tábìlì ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà

      Orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà

      Bẹ́tẹ́lì jẹ́ orúkọ kan lédè Hébérù tó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:​17, 19, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Orúkọ tó bá a mu yìí là ń pe àwọn ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ kárí ayé, tí à ń lò láti darí iṣẹ́ ìwàásù, tí a sì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Orílé-iṣẹ́ wa wà ní ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ sì ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń bójú tó iṣẹ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì là ń pe àwùjọ àwọn tó ń sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bí ìdílé kan, wọ́n ń gbé pa pọ̀, wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n jọ ń jẹun, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.​—Sáàmù 133:1.

      Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn èèyàn ti máa ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. Ní gbogbo ilé Bẹ́tẹ́lì, wàá rí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, tí wọ́n sì ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn láti bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:33) Wọn kì í gba owó oṣù, àmọ́ wọ́n fún wọn ní yàrá, oúnjẹ àti owó ìtìlẹ́yìn tí wọ́n lè fi ra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Gbogbo ẹni tó wà ní Bẹ́tẹ́lì la yan iṣẹ́ fún, yálà ní ọ́fíìsì, ní ilé ìdáná tàbí ní yàrá ìjẹun. Àwọn kan ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé tàbí ibi tí wọ́n ti ń di ìwé pọ̀, àwọn míì ń tọ́jú ilé tàbí kí wọ́n máa fọṣọ, kí wọ́n máa tún nǹkan ṣe tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ míì.

      Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí tí a fi kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì ni láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àpẹẹrẹ kan ni ìwé yìí. A kọ ọ́ lábẹ́ àbójútó Ìgbìmọ̀ Olùdarí, a fi í ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri ayé, a fi ẹ̀rọ tó ń yára tẹ̀ ẹ́ ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì tí a ti ń tẹ̀wé, a sì kó o lọ sí àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà (110,000). Gbogbo iṣẹ́ yìí ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.​—Máàkù 13:10.

      • Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, báwo la sì ṣe ń tọ́jú wọn?

      • Iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú wo ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì kọ̀ọ̀kan ń tì lẹ́yìn?

  • Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 22

      Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?

      Àwọn arákùnrin mélòó kan tó ń bójú tó iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fí ìsì wa lórílẹ̀-èdè Solomon Islands

      Orílẹ̀-èdè Solomon Islands

      Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fí ìsì wa lórílẹ̀-èdè Kánádà

      Orílẹ̀-èdè Kánádà

      Àwọn ọkọ̀ tá a fi ń kó àwọn ìwé wa lọ́ sí ìjọ

      Orílẹ̀-èdè South Africa

      Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn atúmọ̀ èdè, kí wọ́n máa tẹ ìwé ìròyìn, kí wọ́n máa di ìwé pọ̀, kí wọ́n máa tọ́jú àwọn ìwé, kí wọ́n máa gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ tàbí kí wọ́n máa bójú tó àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ agbègbè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.

      Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló ń bójú tó iṣẹ́ ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fa àbójútó ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan lé Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́, àwọn alàgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó kúnjú ìwọ̀n ló máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ yìí. Wọ́n máa ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ìtẹ̀síwájú tó ń bá iṣẹ́ wa láwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà àti ìṣòro tó bá yọjú. Èyí ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ohun tí wọ́n máa gbé jáde àti ohun tó yẹ ká jíròrò ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ lọ́jọ́ iwájú. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán àwọn aṣojú wọn látìgbàdégbà pé kí wọ́n lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò kí wọ́n sì tọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ́nà nípa bí wọ́n ṣe máa bójú tó iṣẹ́ wọn. (Òwe 11:14) Lára àkànṣe ètò tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ìbẹ̀wò náà ni àsọyé tí aṣojú orílé-iṣẹ́ máa ń sọ láti fún àwọn tó ń gbé láwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ń bójú tó níṣìírí.

      Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ tó wà lágbègbè wọn. A fún àwọn arákùnrin kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láṣẹ láti fọwọ́ sí i pé ká dá ìjọ tuntun sílẹ̀. Àwọn kan sì ń bójú tó iṣẹ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó àyíká tó ń sìn láwọn ibi tí ẹ̀ka náà ń bójú tó. Wọ́n máa ń ṣètò àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè, wọ́n ń darí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, wọ́n sì ń rí i dájú pé à ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ìjọ nílò ránṣẹ́ sí wọn. Gbogbo iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa lọ létòlétò.​—1 Kọ́ríńtì 14:​33, 40.

      • Báwo ni àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ṣe ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́?

      • Àwọn iṣẹ́ wo là ń ṣe láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Láti ọjọ́ Monday sí Friday a máa ń mú àwọn àlejò káàkiri ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, kí wọ́n lè rí ohun tí à ń ṣe níbẹ̀. A pè ọ́ pé kí o wá. Tó o bá ń bọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, múra bíi pé ò ń lọ sí ìpàdé ìjọ. Ìgbàgbọ́ rẹ á lágbára sí i tó o bá rí ibi tí à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́