Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní Nísàn 13 ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù mọ̀ pé alẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí òun á fi wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́ kí wọ́n tó pa òun. Ó máa ṣe Ayẹyẹ Ìrékọjá tó kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó sì máa dá ohun kan tí wọ́n á máa rántí sílẹ̀, ìyẹn Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó dájú pé wọ́n ní láti múra sílẹ̀ dáadáa fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Torí náà, ó rán Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n lọ ṣètò àwọn nǹkan tí wọ́n máa lò sílẹ̀. (Lúùkù 22:7-13) Látìgbà yẹn ló ti jẹ́ pé ọdọọdún làwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi ti kà á sí ohun pàtàkì pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. (Lúùkù 22:19) Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní April 3?
Ìmúrasílẹ̀ Tí Gbogbo Wa Máa Ṣe:
- Ṣètò láti kópa dáadáa nínú pípín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi. 
- Ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ, àwọn ìbátan rẹ, àwọn ọmọ iléèwé rẹ, àwọn ará ibiṣẹ́ rẹ àtàwọn míì tó o bá mọ̀, kó o sì pè wọ́n wá. 
- Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a máa ń kà lákòókò Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì ṣàṣàrò lé wọn lórí. 
- Wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kó o sì kí àwọn àlejò káàbọ̀.