-
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́runIṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | December
-
-
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 26, 2005. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ November 7 sí December 26, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 sí 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí la lè ṣe ká bàa lè rí i dájú pé “nítorí ìfẹ́” la fi ń gbani níyànjú? (Fílém. 9) [be-YR ojú ìwé 266]
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà “gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera”? (Títù 1:9) [be-YR ojú ìwé 267, ìpínrọ̀ 1 sí 2]
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa fún àwọn èèyàn níṣìírí, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? [be-YR ojú ìwé 268, ìpínrọ̀ 1 sí 3 àti àpótí]
4. Bíi ti Mósè, báwo ni rírán àwọn ará létí ohun tí Jèhófà ti ṣe lè fún wọn nígboyà? (Diu. 3:28; 31:1-8) [be-YR ojú ìwé 268, ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 269, ìpínrọ̀ 2]
5. Bá a bá ń fìdùnnú sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà ń ṣe nísinsìnyí àti ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, kí nìdí tó fi máa fún àwùjọ tá à ń bá sọ̀rọ̀ níṣìírí? [be-YR ojú ìwé 270 sí 271]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Báwo la ṣe lè fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lókun? [w03-YR 5/15 ojú ìwé 22, ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 2]
7. Irú ọrẹ wo ni inú Ọlọ́run dùn sí? [w03-YR 6/1 ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 2]
8. Báwo lèèyàn ṣe ń kọ́ bá a ṣeé nífẹ̀ẹ́? [w03-YR 7/1 ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 1; ojú ìwé 5, ìpínrọ̀ 4]
9. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ṣoore fáwọn ẹlòmíràn? (Gál. 6:9, 10) [w03-YR 7/15 ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 2 sí 3]
10. Mẹ́nu kan àwọn ìlànà mẹ́ta látinú Bíbélì tó lè ranni lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. [w03-YR 10/15 ojú ìwé 4 sí 5]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ǹjẹ́ ti pé Jèhófà ò jẹ́ kí Dáfídì kọ́ tẹ́ńpìlì fi hàn pé kò fọwọ́ sí àwọn ogun tí Dáfídì jà? (1 Kíró. 22:6-10)
12. Nínú àdúrà tí Sólómọ́nì gbà nígbà tó ń ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, báwo ló ṣe fi hàn pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa ń gbọ́ tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀, ó tún mọ ipò tó ń dojú kọ ẹnì kọ̀ọ̀kan lára àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀? (2 Kíró. 6:29, 30)
13. Kí ni “àwọn ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́” tí 2 Kíróníkà 11:15 mẹ́nu bà?
14. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ní ọdún kẹta Ásà” ni Bááṣà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, tó sì ṣàkóso fún ọdún mẹ́rìnlélógún péré, báwo wá ló ṣe lè jẹ́ pé “ní ọdún kẹrìndínlógójì ìgbà ìjọba Ásà” ni Bááṣà lọ “gbéjà ko Júdà”? (1 Ọba 15:33; 2 Kíró. 16:1)
15. Lọ́nà tó ṣe kedere, báwo ni 2 Kíróníkà 20:22, 23 ṣe ṣàpèjúwe ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí ayé Sátánì?
-
-
Ṣó O Máa Ń Lo Ìwé Ìléwọ́?Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | December
-
-
Ṣó O Máa Ń Lo Ìwé Ìléwọ́?
Ní ọjọ́ kan báyìí, ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá rí ìwé ìléwọ́ tí wọ́n fi ń polongo àsọyé fún gbogbo èèyàn tó dá lórí hẹ́ẹ̀lì. Ọmọkùnrin náà sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: ‘Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa èyí níwọ̀n bó ti jọ pé mo sábà máa ń ṣe ohun tí ó lòdì nígbà gbogbo, mo sì máa ń dààmú púpọ̀ torí mi ò fẹ́ lọ sí hẹ́ẹ̀lì nígbà tí mo bá kú.’ Ó lọ síbi àsọyé náà, lẹ́yìn tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣèrìbọmi ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà. Bí Karl Klein ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Kristẹni nìyẹn, èyí tó ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀, tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ sìn nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ibi ìwé ìléwọ́ lọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀.
Títí di òní olónìí, ìwé ìléwọ́ ṣì jẹ́ irin iṣẹ́ tó dùn-ún jẹ́rìí. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ló ti rí i pé fífún ẹnì kan ní ẹyọ kan jẹ́ ọ̀nà tó dáa láti sọ irú ẹni táwọn jẹ́ ó sì dáa láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Àwọn òbí lè mú káwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù nípa jíjẹ́ kí wọ́n máa fún àwọn èèyàn ní ìwé ìléwọ́ lẹ́nu ọ̀nà. Àwọn akéde tí wọ́n ń fi lẹ́tà wàásù lè sọ àkókò ìpàdé nípa fífi ìwé ìléwọ́ sínú lẹ́tà tí wọ́n bá kọ. Ìwé ìléwọ́ rọrùn láti fi pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn olùfìfẹ́hàn míì láti pésẹ̀ sáwọn ìpàdé wa.
Àlàyé ṣókí nípa ìpàdé ìjọ kọ̀ọ̀kan wà lójú ewé àkọ́kọ́ ìwé ìléwọ́. Níwọ̀n bí kò ti sí àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àkókò ìpàdé nínú ìwé ìléwọ́, ìwọ fúnra rẹ lo máa sọ ìyẹn bó o bá ń fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bó o bá fẹ́ kọ àwọn àlàyé yẹn sí i, ààyè tó o lè kọ ọ́ sí wà nínú ìwé ìléwọ́ náà. Ṣé ọ̀nà tó dáa lo máa ń gbà lo àwọn ìwé ìléwọ́?
-