ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta Ni Olori?
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
    • Arákùnrin Donald Nowills ni wọ́n yàn pé kó máa bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ́yìn tí wọ́n ti fipá kó àwọn míṣọ́nnárì kúrò nílùú, ọmọ ogún [20] ọdún péré ni nígbà yẹn, kò sì tíì ju ọdún mẹ́rin lọ tó ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe alábòójútó àyíká fún oṣù mélòó kan nígbà yẹn, iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣàjèjì sí i. Arákùnrin Nowills ní ọ́fíìsì kékeré kan nílé rẹ̀, igi àti páànù ni wọ́n fi kọ́ ọ, ilẹ̀ eléruku ló sì wà níbẹ̀. Ibi tó léwu gan-an ní àgbègbè Gualey nílùú Ciudad Trujillo ni ọ́fíìsì náà wà. Òun àti Félix Marte ló máa ń ṣe ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ fún àwọn ará ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà.

      Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111

      Ile-Iṣọ Na ti ọdún 1958 tí wọ́n fi ẹ̀rọ ṣe àdàkọ rẹ̀

      Arábìnrin Mary Glass tí Enrique, ọkọ rẹ̀ wà lẹ́wọ̀n ní gbogbo ìgbà yẹn náà máa ń ran Arákùnrin Nowills lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Màá ṣíwọ́ níbiiṣẹ́ tó bá di aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́, màá lọ sí ọ́fíìsì Arákùnrin Nowills kí n lè fi ẹ̀rọ tẹ Ilé Ìṣọ́. Arákùnrin Nowills á wá fi ẹ̀rọ ṣe ẹ̀dà ìwé náà. Lẹ́yìn náà ni arábìnrin kan tó wá láti Santiago tá a máa ń pè ní ‘áńgẹ́lì,’ á wá kó àwọn ìwé ìròyìn náà sí ìsàlẹ̀ òfìfo garawa òróró. Lẹ́yìn náà, á da aṣọ bo ìwé náà, á kó pákí, ọ̀dùnkún tàbí kókò sórí aṣọ náà, kó tó wá da àpò ìdọ̀họ bò ó. Lẹ́yìn yẹn, á gbé ẹrù náà wọnú ọkọ̀ èrò lọ sí apá àríwá orílẹ̀-èdè náà, á wá fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà kan ìwé náà. Àwọn ìdílé tó wà níbẹ̀ máa ń gba ìwé náà lọ́wọ́ ara wọn kí wọ́n lè fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.”

      Arábìnrin Mary sọ pé: “A máa ń ṣọ́ra gan-an torí pé àwọn aṣojú ìjọba wà káàkiri ìgboro tí wọ́n fẹ́ mọ ibi tá a ti ń tẹ Ilé Ìṣọ́. Àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn já sí. Jèhófà máa ń fi ààbò rẹ̀ bò wá nígbà gbogbo.”

      Àpótí tó wà ní ojú ìwé 112, 113
  • Won O Beru Pe Won Le Mu Won
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
    • ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

      Won Ò Bẹ̀rù Pé Wọ́n Lè Mú Won

      Wọ́n ‘Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra bí Ejò àti Ọlọ́rùn-Mímọ́ bí Àdàbà’

      Ó ṣe pàtàkì pé káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà nígbà ìfòfindè, àmọ́ nǹkan le koko fáwọn olùjọsìn tòótọ́ lórílẹ̀-èdè náà nígbà yẹn. Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n mú tí wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n fún àkókò tó yàtọ̀ síra.

      Juanita Borges sọ pé: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dún 1953, mo mọ̀ dáadáa pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n mú èmi náà torí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Nígbà tí mo lọ kí Arábìnrin Eneida Suárez ní oṣù November ọdún 1958, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wá mú wa, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé à ń ṣèpàdé. Wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta, wọ́n sì ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa san ọgọ́rùn-ún peso, tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] náírà nígbà yẹn, gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.”

      Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 115

      Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará wa.

      Ìjọba ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwa Ẹlẹ́rìí má bàa máa ṣe ìpàdé, àmọ́ ìyẹn ò dá àwọn ará wa dúró. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ní láti ‘jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra bí ejò àti ọlọ́rùn-mímọ́ bí àdàbà.’ (Mát. 10:16) Andrea Almánzar sọ pé: “A kì í dé sípàdé nígbà kan náà. Ilẹ̀ sì máa ń ṣú gan-an ká tó pa dà sílé torí pé a kì í fẹ́ kúrò nígbà kan náà, kí wọ́n má bàa fura sí wa.”

      Jeremías Glass kò ju ọmọ ọdún méje lọ nígbà tó di akéde lọ́dún 1957. Ẹ̀wọ̀n ni León, bàbá rẹ̀ wá nígbà tí wọ́n bí i. Ó rántí bí wọ́n ṣe máa ń rọra ṣèpàdé ní ìdákọ́ńkọ́ nílé wọn àtàwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe káwọn aláṣẹ má bàa rí wọn. Jeremías ṣàlàyé pé: “Wọ́n máa ń pín káàdì kékeré tí wọ́n ti kọ nọ́ńbà sí tó máa jẹ́ kí kálukú mọ ìgbà tóun máa jáde. Bí ìpàdé bá ti parí, bàbá mi máa ń ní kí n dúró sẹ́nu ọ̀nà kí n lè máa wo nọ́ńbà tó wà nínú káàdì àwọn tó bá ń jáde, kí n sì lè máa sọ fún wọn pé kí wọ́n jáde ní méjì-méjì, kí wọ́n má sì gba ọ̀nà ibì kan náà.”

      Ohun míì tá a tún máa ń ṣe ni pé, a máa ń fi ìpàdé sí àkókò tí àwọn tó ń ṣọ́ wa kò ní fi bẹ́ẹ̀ rí wa. Bí àpẹẹrẹ, Pablo González ló kọ́ Mercedes García, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọmọ ọdún méje péré ni Mercedes nígbà tí ìyá rẹ̀ ṣàìsí, ẹ̀wọ̀n sì ni bàbá rẹ̀ wà nígbà yẹn. Ó wá ku òun, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ márùn-ún àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́rin. Ọdún 1959 ni Mercedes ṣèrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Aago mẹ́ta ààbọ̀ òru ni wọ́n sọ àsọyé ìrìbọmi rẹ̀, káwọn aláṣẹ má bàa fura sí wọn. Ilé arákùnrin kan ni wọ́n ti sọ àsọyé náà, wọ́n wá lọ rì í bọmi ní Odò Ozama tó ṣàn gba olú ìlú náà kọjá. Mercedes sọ pé: “Ìgbà tá à ń pa dà lọ sílé láago márùn-ún ààbọ̀ ìdájí làwọn ará àdúgbò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jí.”

      À Ń Pọ̀ Sí I Láìka Inúnibíni Sí

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe inúnibíni sí wa lọ́nà líle koko tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ wa láìdáa, iye akéde fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po méjì nígbà ìfòfindè náà.

      • 1950 - 292

      • 1960 - 495

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́