Ohun Tí Bíbélì Sọ
Tá ni Èṣù?
ṢÉ WÀÁ SỌ PÉ Èṣù jẹ́ . . .
- Ẹ̀mí àìrí kan? 
- Èrò ibi tó wà lọ́kàn èèyàn? 
- Tàbí pé kò sí Èṣù? 
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Èṣù bá Jésù sọ̀rọ̀, ó sì “dẹ ẹ́ wò.” (Mátíù 4:1-4) Èyí fi hàn pé Èṣù kì í ṣe èrò ibi tó wà lọ́kàn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú kan ni.
OHUN MÍÌ TÁ A LÈ KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ
- Áńgẹ́lì mímọ́ ni Èṣù nígbà tí Ọlọ́run dá a, àmọ́ ‘kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Ó di òpùrọ́, ó sì ta ko Ọlọ́run. 
- Àwọn áńgẹ́lì míì gbè sẹ́yìn Sátánì.—Ìṣípayá 12:9. 
- Èṣù ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé òun kò sí.—2 Kọ́ríńtì 4:4. 
Ṣé Èṣù lè darí àwọn èèyàn?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ ẹ̀tàn lásán ni pé Èṣù lágbára lórí àwọn èèyàn. Àwọn míì sì ń máa ń bẹ̀rù pé kí Èṣù má kó wọnú àwọn. Kí lèrò tiẹ̀?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Èṣù máa ń tan àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ kò lè darí gbogbo èèyàn.
OHUN MÍÌ TÁ A LÈ KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ
- Èṣù máa ń díbọ́n kó lè mú káwọn èèyàn gba ohun tó fẹ́.—2 Kọ́ríńtì 11:14. 
- Láwọn ìgbà míì, àwọn ẹ̀mí Èṣù máa ń darí àwọn èèyàn kan.—Mátíù 12:22. 
- Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “kọ ojú ìjà sí Èṣù.” —Jákọ́bù 4:7.