ORIN 95
Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
(Òwe 4:18)
- 1. Àwọn wòlíì àtijọ́ fẹ́ mọ Kristi, - Ẹni tó jẹ́ káyé nírètí. - Ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́rìí sí i pé yóò wá, - Yóò jẹ́ káráyé rítùúsílẹ̀. - Ní báyìí, Mèsáyà ti ń jọba lọ́run, - Ẹ̀rí tó dájú fèyí hàn. - Àǹfààní ló jẹ́ láti m’òtítọ́ yìí, - Òótọ́ táwọn áńgẹ́lì fẹ́ mọ̀! - (ÈGBÈ) - Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i - Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan. - Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá; - Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn. 
- 2. Ẹrú olóòótọ́ tí Jésù yàn sípò, - Ń fún wa lóúnjẹ lákòókò tó yẹ. - Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Ló ń fa olóòótọ́ ọkàn mọ́ra. - Ìmọ́lẹ̀ túbọ̀ ń tàn sípa ọ̀nà wa, - Ẹsẹ̀ wa kò kúrò lọ́nà. - A dúpẹ́, Jèhófà, Orísun ‘mọ́lẹ̀, - Títí láé la ó máa rìn lọ́nà rẹ. - (ÈGBÈ) - Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i - Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan. - Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá; - Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn. 
(Tún wo Róòmù 8:22; 1 Kọ́r. 2:10; 1 Pét. 1:12.)