ORIN 129
A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jésù Aṣáájú - Wa fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. - Ó nífaradà, - Ìrètí tó ní fún un láyọ̀. - Ó ń retí bí ‘lérí - Bàbá rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ. - (ÈGBÈ) - Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á, - Ká fìwà jọ Jésù. - Jèhófà wà pẹ̀lú wa, - Ká máa fara dà á títí dé òpin. 
- 2. Ọ̀pọ̀ àdánwò - Là ńdojú kọ bá a ṣe ńsin Jáà. - Ká máa fara dà á; - Ayọ̀ ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. - Ká má ṣe rẹ̀wẹ̀sì, - Ìgbà ọ̀tun dé tán. - (ÈGBÈ) - Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á, - Ká fìwà jọ Jésù. - Jèhófà wà pẹ̀lú wa, - Ká máa fara dà á títí dé òpin. 
- 3. A fẹ́ máa bá a lọ - Láti fara da àdánwò. - Ká máa fòótọ́ sìn, - Ká má bẹ̀rù, ká má fòyà. - Ká jẹ́ olótìítọ́; - Ká fara dà á dópin. - (ÈGBÈ) - Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á, - Ká fìwà jọ Jésù. - Jèhófà wà pẹ̀lú wa, - Ká máa fara dà á títí dé òpin. 
(Tún wo Ìṣe 20:19, 20; Jém. 1:12; 1 Pét. 4:12-14.)