ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 1-4
“Mo Wà Pẹ̀lú Rẹ Láti Dá Ọ Nídè”
Bíi Ti Orí Ìwé
	Ó ṣeé ṣe kí Jeremáyà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] nígbà tí Jèhófà yàn án láti di wòlíì. Jeremáyà ronú pé òun ò tóótun láti ṣe iṣẹ́ náà, àmọ́ Jèhófà mú un dá a lójú pé òun máa tì í lẹ́yìn.
- 647 - Jeremáyà di wòlíì 
- 607 - Jerúsálẹ́mù pa run 
- 580 - Ìwé kíkọ parí 
Gbogbo déètì jẹ́ ṣáájú Sànmánì Kristẹni