ORIN 74
Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà
- 1. Orin ayọ̀ ìṣẹ́gun ni orin yìí. - Ó ń gbé Olódùmarè Ọba ga. - Jẹ́ ká jọ kọ ọ́; ó ń fún wa ní ìrètí, - Ó sì ń kọ́ wa pé ká dúró ṣinṣin. - (ÈGBÈ) - Ẹ wọlé wá síwájú Jáà. - Ẹ kéde pé Jésù lọba. - Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà. - Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀. 
- 2. À ń forin tuntun yìí kéde fáráyé - Pé Jésù Kristi ti ń jọba lọ́run. - Àwọn kan wà tó máa bá Jésù jọba. - Ọlọ́run ti sọ wọ́n di àtúnbí. - (ÈGBÈ) - Ẹ wọlé wá síwájú Jáà. - Ẹ kéde pé Jésù lọba. - Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà. - Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀. 
- 3. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ lè mọ orin yìí. - Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọrùn, ó sì dùn mọ́ni. - Ọ̀pọ̀ ti mọ orin yìí kárí ayé, - Wọ́n sì tún ń ké sí àwọn mìíràn pé: - (ÈGBÈ) - Ẹ wọlé wá síwájú Jáà. - Ẹ kéde pé Jésù lọba. - Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà. - Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀. 
(Tún wo Sm. 95:6; 1 Pét. 2:9, 10; Ìfi. 12:10.)