ORIN 52
Ìyàsímímọ́ Kristẹni
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ̀dá - Àgbáálá ayé yìí. - Tirẹ̀ layé àti ọ̀run, - Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni. - Ó fún wa ní èémí ìyè, - Ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé, - Òun nìkan ló yẹ ká fìyìn fún, - Òun nìkan ló yẹ ká sìn. 
- 2. Jésù Kristi ṣèrìbọmi - Láti módodo ṣẹ. - Ó gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé: - ‘Mo dé wá ṣèfẹ́ rẹ.’ - Bó ṣe jáde nínú omi, - Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án. - Olóòótọ́ ni, ó gbàdúrà pé: - ‘Bàbá, jẹ́ kífẹ̀ẹ́ rẹ ṣẹ.’ 
- 3. Iwájú rẹ la wà, Bàbá. - À ń yin orúkọ rẹ. - A ya ara wa sí mímọ́ - Pẹ̀lú ‘rẹ̀lẹ̀ ọkàn. - O fún wa lọ́mọ bíbí rẹ; - Ó fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. - Torí náà, ìfẹ́ Rẹ la ó máa ṣe - Jálẹ̀ ọjọ́ ayé wa. 
(Tún wo Mát. 16:24; Máàkù 8:34; Lúùkù 9:23.)