ORIN 93
Bù Kún Ìpàdé Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ìbùkún rẹ ṣe pàtàkì - Bá a ṣe ń pé jọ fún ‘jọsìn. - A bẹ̀bẹ̀ pé kó o bù kún wa, - Kẹ́mìí rẹ wà pẹ̀lú wa. 
- 2. Jọ̀ọ́, Jèhófà, fi Ọ̀rọ̀ rẹ - Kọ́ wa, kó wọ̀ wá lọ́kàn. - Kọ́ ahọ́n wa ká lè jẹ́rìí, - Ká lè jọ́sìn rẹ dáadáa. 
- 3. Jèhófà, bù kún ‘pàdé wa, - Jọ̀ọ́, jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. - Kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa - Máa gbé orúkọ rẹ ga. 
(Tún wo Sm. 22:22; 34:3; Àìsá. 50:4.)