ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 49-50
Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Ó sì Ń Fìyà Jẹ Àwọn Agbéraga
- Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà máa fò fáyọ̀ nígbà tí Jèhófà bá mú wọn kúrò nígbèkùn 
- Wọ́n á tún mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ lákọ̀tun, wọ́n á sì rìnrìn àjò tó jìn pa dà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ 
- Bábílónì kò ní lọ láìjìyà torí ìwà ìkà tó burú jáì tó hù sí àwọn èèyàn Jèhófà 
- Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ní ìmúṣẹ, Bábílónì di ahoro, kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ títí dòní