ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 21-23
Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ Lábẹ́ Òfin Ni Ọba Tọ́ Sí
Bíi Ti Orí Ìwé
	Jésù ni ẹni tí Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ọba tọ́ sí “lọ́nà òfin.”
- Láti inú ẹ̀yà wo ni Mèsáyà ti wá? 
- Ta ni Jèhófà sọ fún pé ìjọba rẹ̀ máa wà títí láé? 
- Láti apá ọ̀dọ̀ ta ni Mátíù ti ṣàlàyé ìlà ìdílé tí wọ́n ti máa bí Jésù láti fi hàn pé ó lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì?