-
Máa fi Òtítọ́ Kọ́niÌwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—2016 | August
-
-
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni
Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun kan á máa jáde nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, àkòrí rẹ̀ ni “Máa Fi Òtítọ́ Kọ́ni.” A fẹ́ ká máa fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun yìí wàásù òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn, ò máa jẹ́ lọ́nà ìbéèrè, lẹ́yìn náà, a máa fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tì í lẹ́yìn.
Tá a bá rí i pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a lè fún un ní ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tàbí ká fi ọ̀kan lára àwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo hàn án, èyí á jẹ́ kó lè máa fojú sọ́nà fún ìgbà míì tá a máa pa dà wá. Ẹ jẹ́ ká tètè pa dà lọ bẹ̀ ẹni náà wò láàárín ọjọ́ díẹ̀ ká lè máa bá ìjíròrò wa nìṣó. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tuntun yìí àti iṣẹ́ tá a yàn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa dá lórí àwọn ohun tó wà nínú orí kọ̀ọ̀kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ Wa? lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì wà níbẹ̀ tó máa jẹ́ ká lè lo Bíbélì nìkan nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọ̀nà kan ṣoṣo ló lọ sí ìyè. (Mt 7:13, 14) Onírúurú àwọn èèyàn tó wà láti ibi tó wá yàtọ̀ síra là ń wàásù fún, ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ń ṣe, torí náà, àwọn òtítọ́ Bíbélì tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa nífẹ̀ẹ́ sí ló yẹ ká bá wọn sọ. (1Ti 2:4) Bá a ṣe ń fi onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i, a ó túbọ̀ jáfáfá nínú bí a ṣe ń “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́,” ìyẹn sì máa jẹ́ ká kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.—2Ti 2:15.
-
-
Àkànṣe Ìwàásù Láti Pín Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Lóṣù SeptemberÌwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—2016 | August
-
-
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àkànṣe Ìwàásù Láti Pín Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ Lóṣù September
Gbogbo èèyàn tó wà láyé ló nílò ìtùnú. (Onw 4:1) Lóṣù September, a máa pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lákànṣe, àkòrí Ilé Ìṣọ́ yẹn máa dá lorí ìtùnú. Ẹ rí ì dájú pé ẹ pín ìwé ìròyìn yìí fún gbogbo èèyàn. Ká tó lè tù àwọn èèyàn nínú, a ní láti rí wọn ká sì bá wọn sọ̀rọ̀, torí náà, a ò ní fí ìwé ìròyìn yìí sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé.
OHUN TÁ A LÈ SỌ
“Gbogbo wa la máa ń nílò ìtùnú lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n ibo lẹ rò pé a ti lè rí ìtùnú? [Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.] Ilé Ìṣọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe pèsè irú ìtùnú bẹ́ẹ̀.”
Bí ẹni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tó sì gba ìwé ìròyìn náà, . . .
FI FÍDÍÒ KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ? HÀN ÁN
Lẹ́yìn náà, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
MÚRA RẸ̀ SÍLẸ̀ DE ÌGBÀ TÓ O MÁA PA DÀ WÁ
Bi í ní ìbéèrè tí wàá dáhùn nígbà tó o bá pa dà wá, irú bíi “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?”
-