ORIN 78
‘Máa Kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Àǹfààní ńlá la ní láti - Kọ́ni lọ́r’Ọlọ́run. - Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, - Ó máa ń dùn mọ́ni gan-an. - Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn - Lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀r’Ọlọ́run, - À ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa - Sún mọ́ Ọlọ́run wa. 
- 2. Àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ - Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa; - Ká sì jẹ́ kó máa hàn nínú - Ìgbésí ayé wa, - Káwọn ẹlòmíràn lè rí - Ìwà rere wa yìí. - Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn yìí - Là ń kọ́ ara wa náà. 
- 3. Jèhófà ti pèsè àwọn - Ohun tá a máa nílò. - Àdúrà ń kópa pàtàkì - Ká lè ṣàṣeyọrí. - A mọ̀ dájú pé Jèhófà - Máa gbọ́ àdúrà wa. - Láìpẹ́, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà - Máa lè kọ́ àwọn mí ì! 
(Tún wo Sm. 119:97; 2 Tím. 4:2; Títù 2:7; 1 Jòh. 5:14.)