ORIN 77
Ìmọ́lẹ̀ Nínú Ayé Tó Ṣókùnkùn
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Nínú ayé òkùnkùn yìí, - Ìmọ́lẹ̀ kan ń tàn yòò. - Ọjọ́ iwájú aláyọ̀ - Ti fẹ́rẹ̀ẹ́ wọlé dé. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ ìwàásù wa - Ń tàn yòò kárí ayé yìí - Bí ‘mọ́lẹ̀ òwúrọ̀ - Kò ní sókùnkùn mọ́; - Láìpẹ́, ọjọ́ aláyọ̀ - Yóò wọlé dé. 
- 2. Ó yẹ ká jí àwọn tó ń sùn - Torí àkókò ń lọ. - Ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè - La òpin tó ń bọ̀ já. - (ÈGBÈ) - Iṣẹ́ ìwàásù wa - Ń tàn yòò kárí ayé yìí - Bí ‘mọ́lẹ̀ òwúrọ̀ - Kò ní sókùnkùn mọ́; - Láìpẹ́, ọjọ́ aláyọ̀ - Yóò wọlé dé. 
(Tún wo Jòh. 3:19; 8:12; Róòmù 13:11, 12; 1 Pét. 2:9.)