ORIN 97
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Ká lè máa wà láàyè. - Oúnjẹ tara nìkan kò tó - Láti gbẹ́mìí wa ró. - Tá a bá ńgbọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, - Ayé wa yóò dára. - (ÈGBÈ) - Oúnjẹ tara nìkan kò tó - Láti gbẹ́mìí wa ró. - Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì - Ká lè máa wà láàyè. 
- 2. Ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ - Kọ́ wa lọ́pọ̀ ẹ̀kọ́. - Ó sọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ - Tí wọ́n ní ìgbàgbọ́. - Àpẹẹrẹ wọn ńfún wa lókun; - Ó ńgbé ‘gbàgbọ́ wa ró. - (ÈGBÈ) - Oúnjẹ tara nìkan kò tó - Láti gbẹ́mìí wa ró. - Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì - Ká lè máa wà láàyè. 
- 3. Táa bá ńka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, - Yóò máa tù wá nínú. - Tí a bá kojú ìṣòro, - Ó máa ràn wá lọ́wọ́. - Ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run - Máa wà ní ọkàn wa. - (ÈGBÈ) - Oúnjẹ tara nìkan kò tó - Láti gbẹ́mìí wa ró. - Ọ̀r’Ọlọ́run ṣe pàtàkì - Ká lè máa wà láàyè. 
(Tún wo Jóṣ. 1:8; Róòmù 15:4.)