-
Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé YìíIlé Ìṣọ́—2012 | September 1
-
-
© 2012 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Gbogbo ẹ̀tọ́ jẹ́ tiwa.
-
-
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?Ilé Ìṣọ́—2012 | September 1
-
-
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
“Obìnrin ló fa ẹ̀ṣẹ̀ sínú ayé, òun ni ó fa ikú wá sórí gbogbo wa pátá.”—ÌWÉ ECCLESIASTICUS, ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KEJÌ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.
“Ẹ̀yin ni ẹ kọ́kọ́ gba èṣù láyè: ẹ̀yin ni ẹ kọ́kọ́ lọ jẹ èso igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀: ẹ̀yin lẹ kọ́kọ́ tẹ òfin Ọlọ́run lójú . . . Ẹ̀yin ni ẹ bá ọkùnrin tó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run kanlẹ̀ wẹ́rẹ́.”—TERTULLIAN, NÍNÚ ÌWÉ ON THE APPAREL OF WOMEN, TÓ KỌ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KEJÌ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.
INÚ Bíbélì kọ́ ni wọ́n ti rí àwọn àyọkà tó ti wà tipẹ́tipẹ́ yìí. Láti ọdúnmọ́dún ni àwọn èèyàn ti ń lo irú àwọn àyọkà yìí láti fi dá ṣíṣàìka àwọn obìnrin sí láre. Kódà lóde òní, àwọn agbawèrèmẹ́sìn ṣì máa ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ inú ìwé ẹ̀sìn láti fi ṣe ẹ̀rí pé ó bófin mu láti máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba, torí wọ́n ní àwọn obìnrin ló fa àwọn ìṣòro tó dé bá gbogbo aráyé. Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run pète pé kí àwọn ọkùnrin máa fi ojú àwọn obìnrin gbolẹ̀, kí wọ́n sì máa kàn wọ́n lábùkù? Kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.
Ṣé Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn obìnrin ni?
Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù” ni Ọlọ́run gé “ègún” fún. (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:14) Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé Ádámù yóò “jọba lé” ìyàwó rẹ̀ lórí, kì í ṣe pé ó ń fi hàn pé òun fọwọ́ sí bí àwọn ọkùnrin ṣe ń tẹ àwọn obìnrin lórí ba. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ṣe ló kàn ń sọ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe fún tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn.
Nítorí náà, bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ojú àwọn obìnrin gbolẹ̀ kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àbájáde jíjẹ́ tí àwa èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Bíbélì kò fọwọ́ sí èrò àwọn tó sọ pé àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba kí ìyẹn lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Róòmù 5:12.
Ǹjẹ́ Ọlọ́run dá obìnrin ní ẹni tó rẹlẹ̀ sí ọkùnrin?
Rárá. Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Èyí fi hàn pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́nà tí a ó fi lè máa hùwà bíi tirẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tó yàtọ̀ síra ní ti ìrísí wọn àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn, irú ìtọ́ni kan náà ni wọ́n jọ gbà, ẹ̀tọ́ kan náà ni wọ́n sì jọ ní lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-31.
Kí Ọlọ́run tó dá Éfà ló ti sọ pé: “Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un [ìyẹn Ádámù], gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ṣé ohun tí ọ̀rọ̀ náà “àṣekún” ń fi hàn ni pé obìnrin rẹlẹ̀ sí ọkùnrin? Rárá, torí pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí àṣekún nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí “ẹnì kejì” tàbí ‘olùrànlọ́wọ́ tó bá ọkùnrin ṣe rẹ́gí.’ A lè fi ohun tí à ń sọ yìí wé bí iṣẹ́ dókítà oníṣẹ́ abẹ àti iṣẹ́ oníṣègùn
-