ORIN 67
Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà
- 1. Jáà ti pàṣẹ fún wa lónìí, - Ó sì yẹ ká ṣègbọràn sáṣẹ rẹ̀. - Ká máa múra ọkàn wa sílẹ̀ - Láti sọ̀r’Ọlọ́run nígbàkigbà. - (ÈGBÈ) - Ṣáà máa wàásù - Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́. - Máa wàásù; - Òpin ayé ti dé tán. - Máa wàásù; - Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. - Máa wàásù - Kárí ayé. 
- 2. Àkókò ìṣòro yóò wà. - Wọ́n lè ṣe inúnibíni sí wa. - Bí wọn kò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, - Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run wa. - (ÈGBÈ) - Ṣáà máa wàásù - Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́. - Máa wàásù; - Òpin ayé ti dé tán. - Máa wàásù; - Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. - Máa wàásù - Kárí ayé. 
- 3. Àkókò tó dẹrùn yóò wà, - Táa máa ní àǹfààní láti kọ́ni. - Ká wàásù kí wọ́n lè rígbàlà, - Kórúkọ Jèhófà lè di mímọ́. - (ÈGBÈ) - Ṣáà máa wàásù - Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́. - Máa wàásù; - Òpin ayé ti dé tán. - Máa wàásù; - Kọ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. - Máa wàásù - Kárí ayé. 
(Tún wo Mát. 10:7; 24:14; Ìṣe 10:42; 1 Pét. 3:15.)