-
Ìlànà Bíbélì Wúlò Títí LáéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018 | No. 1
-
-
aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.”—Sáàmù 90:10.
Bíbélì ran Delphine lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan nira fún un yìí. Ara sì tù ú gan-an. Bí a ṣe máa rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ mẹ́ta tó kù, ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé Bíbélì ti ran àwọn lọ́wọ́ lọ́nà tó pọ̀ gan-an nígbà táwọn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ lásìkò ìṣòro. Wọ́n ti rí i pé ńṣe ni Bíbélì dà bí ohun ìṣẹ̀ǹbáyé irú èyí tá a fi ṣàpèjúwe níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Kò dà bí ọ̀pọ̀ ìwé tó máa ń gbó tí kì í sì í bóde mu mọ́. Ṣé torí pé ohun èlò kan tó yàtọ̀ ni wọ́n fi ṣe Bíbélì ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, kì í ṣe ti àwa èèyàn lásán?—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé ẹ̀mí àwa èèyàn kì í gùn, a sì máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Tó o bá ní ìṣòro tó ń bá ẹ fínra, ọ̀dọ̀ ta lo máa ń lọ kó o lè rí ìtùnú, ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn tó wúlò?
Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà mẹ́ta tí Bíbélì lè gbà ṣe ẹ́ láǹfààní nígbèésí ayé rẹ. Ó máa kọ́ ẹ bó o ṣe lè
yẹra fún ìṣòro tó bá ṣeé ṣe.
yanjú wàhálà nígbà tó bá wáyé.
fara da àwọn ipò nǹkan tí kò ṣeé yí pa dà.
A máa sọ̀rọ̀ lórí kókó mẹ́ta yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kù.
-
-
Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018 | No. 1
-
-
ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN
BÓ TILẸ̀ JẸ́ PÉ BÍBÉLÌ KÌ Í ṢE ÌWÉ ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN, ÀWỌN ÌLÀNÀ KAN WÀ NÍNÚ RẸ̀ TÓ BÁ Ọ̀RỌ̀ ÌLERA TÒDE ÒNÍ MU.
Yíya àwọn tó ní àrùn sọ́tọ̀.
Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje [700] sẹ́yìn tí oríṣiríṣi àrùn ń yọjú ni àwọn dókítà wá bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ̀ lé ìlànà yìí, wọ́n sì gbà pé ó wúlò títí dòní.—Léfítíkù, orí 13 àti 14.
Fífọ ọwọ́ lẹ́yìn téèyàn bá fi ọwọ́ kan òkú.
Ìgbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ń parí lọ làwọn dókítà ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé kò dáa kí wọ́n fi ọwọ́ kan òkú, kí wọ́n tún wá fi ọwọ́ yẹn tọ́jú aláìsàn láìjẹ́ pé wọ́n fọwọ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ti fa ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Síbẹ̀, Òfin Mósè sọ pé aláìmọ́ ni ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ kan òkú. Kódà òfin náà dìídì sọ pé kí wọ́n fi omi wẹ ẹni náà mọ́ lọ́nà àṣà. Ó dájú pé àwọn àṣà ẹ̀sìn yẹn jẹ́ kí àwọn tó tẹ̀ lé òfin náà ní ìlera tó dára.—Númérì 19:11, 19.
Bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìgbọ̀nsẹ̀.
Ọdọọdún ni ìgbẹ́ gbuuru ń pa èyí tó ju ìdajì mílíọ̀nù àwọn ọmọdé torí pé àwọn tó wà láyìíká wọn kì í bójú tó ìgbọ̀nsẹ̀ lọ́nà tó yẹ. Òfin Mósè sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, kó sì jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbé.—Diutarónómì 23:13.
Ìgbà tó yẹ kí wọ́n dádọ̀dọ́ fún ọmọ.
Òfin Ọlọ́run sọ ní pàtó pé wọ́n gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ ọmọkùnrin ní ọjọ́ kẹjọ tí wọ́n bí i. (Léfítíkù 12:3) Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n bá bí ọmọ jòjòló ni ẹ̀jẹ̀ tó lè tètè dá lára rẹ̀ bó ṣe yẹ. Ní àwọn ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, tí ìmọ̀ ìṣègùn kò tíì jinlẹ̀ tó tòde òní, ó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n dúró di ẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó dádọ̀dọ́ ọmọ fún àǹfààní ọmọ náà.
Bí ìlera ara àti ti ọpọlọ ṣe tan mọ́ra.
Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ ìlera àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé èèyàn máa ní ìlera tó dáa tí inú èèyàn bá ń dùn, tó ní ẹ̀mí pé nǹkan ṣì máa dáa, tó ń dúpẹ́ oore, tó sì ní ẹ̀mí ìdáríjì. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.”—Òwe 17:22.
-