ORIN 99
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará; - A wà kárí ayé. - Ẹlẹ́rìí òótọ́ ni wá, - À ń pàwà títọ́ mọ́. - Ẹgbẹẹgbẹ̀rún niye wa; - Ṣe la túbọ̀ ń pọ̀ sí i. - Látibi gbogbo kárí ayé, - À ń fògo f’Ọ́lọ́run. 
- 2. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará; - À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. - Ìhìnrere aláyọ̀ - Là ń kéde fáráyé. - Nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá. - Ká má ṣe sorí kọ́. - Jésù ọ̀gá wa ń mára tù wá; - Ó ń fọkàn wa balẹ̀. 
- 3. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ará; - Jáà ló ń dáàbò bò wá. - À ń jọ́sìn Ọlọ́run wa - Nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀. - Ojoojúmọ́ là ń pọ̀ sí i. - À ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. - A sì ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́; - À ń sìn ín tọ̀sántòru. 
(Tún wo Àìsá. 52:7; Mát. 11:29; Ìfi. 7:15.)