ORIN 36
À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Òwe 4:23)
- 1. Ká máa dáàbò bo ọkàn wa - Tí a bá fẹ́ ríyè. - Ọlọ́run ń yẹ ọkàn wa wò, - Ó mọ ẹni tá a jẹ́. - Tá a bá jẹ́ kọ́kàn wa tàn wá, - Ó lè ṣì wá lọ́nà. - Ká jẹ́ kí èrò inú wa - Bá ti Jèhófà mu. 
- 2. À ń gbàdúrà tó tọkàn wá, - À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jáà. - Ìgbà gbogbo là ń fìyìn fún un - Torí pó ń tọ́jú wa. - À ń ṣègbọràn sáwọn ẹ̀kọ́ - Tí Jèhófà ń kọ́ wa. - Tọkàntọkàn là ń ṣèfẹ́ rẹ̀; - A dúró ṣinṣin sí i. 
- 3. Ohun tó tọ́ là ń fọkàn rò, - À ń sá féròkerò. - À ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, - Ayé wa ń dára sí i. - Ọkàn wa balẹ̀ torí pé - Jáà fẹ́ràn olóòótọ́. - A ó máa fi tọkàntọkàn sìn ín - Títí ayérayé. 
(Tún wo Sm. 34:1; Fílí. 4:8; 1 Pét. 3:4.)