ORIN 12
Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ògo àtìyìn yẹ ọ́, Jèhófà, - Ẹniire tó ń ṣòdodo - Ní gbogbo ọ̀nà lo jẹ́. - Agbára, ọgbọ́n àtìfẹ́ rẹ pọ̀, - Ọlọ́run ayérayé. 
- 2. Bàbá, àánú rẹ máa ńtù wá lára. - O máa ń gbọ́ àdúrà wa - Báa tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. - Ò ń gbẹ́mìí wa ró, o sì tún ńkọ́ wa; - Atóófaratì ni ọ́! 
- 3. Àwọn ẹ̀dá lọ́run àti láyé, - Wọ́n ń forin yìn ọ́ lógo; - Àwa náà yóò máa yìn ọ́. - Atóbilọ́lá, jọ̀ọ́ gba ìyìn wa. - Tọkàntọkàn là ń yìn ọ́. 
(Tún wo Diu. 32:4; Òwe 16:12; Mát. 6:10; Ìfi. 4:11.)