ORIN 7
Jèhófà Ni Agbára Wa
- 1. Okun wa, agbára wa, ààbò wa; - Jèhófà, ayọ̀ wa, ìgbàlà wa. - A ó fayọ̀ sọ nípa rẹ fáráyé, - Bóyá wọ́n fẹ́ gbọ́ tàbí wọn kò fẹ́. - (ÈGBÈ) - Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa, - A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ. - Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù, - Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù. 
- 2. Ẹlẹ́rìí rẹ tá a jẹ́ ńmú ká láyọ̀. - A mọ òtítọ́ àtohun tó tọ́. - Àṣẹ rẹ tó wà nínú Bíbélì - Mú ká lè kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ. - (ÈGBÈ) - Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa, - A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ. - Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù, - Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù. 
- 3. Bí Èṣù ń gàn wá, a kò ní bẹ̀rù - Títí láé la ó máa fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ. - Bí Sátánì bá tiẹ̀ fẹ́ gbẹ̀mí wa, - Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí ọ. - (ÈGBÈ) - Ìwọ l’Àpáta wa àt’Okun wa, - A ó jẹ́ káráyé morúkọ rẹ. - Jèhófà, ìwọ lo lágbára jù, - Ìwọ nibi ààbò wa gíga jù. 
(Tún wo 2 Sám. 22:3; Sm. 18:2; Àìsá. 43:12.)