ORIN 90
Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Bá a ṣe ńkóra jọ láti jọ́sìn, - Tí à ń fòótọ́ inú sin Jáà, - À ń ru àwọn ará wa sókè; - Sífẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ rere. - Ibi ààbò ni ìjọ wa jẹ́, - Ọkàn wa máa ń balẹ̀ níbẹ̀. - Àlàáfíà wà láàárín gbogbo wa, - A nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. 
- 2. Ọ̀rọ̀ tá a sọ lákòókò tó yẹ - Máa ń tura, ó sì ńgbéni ró! - Ó máa ń jẹ́ káwọn tó sorí kọ́ - Rítùnú, kí wọ́n sì láyọ̀. - Bí a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan, - À ń wọ̀nà fún ayé tuntun! - À ń gbéra wa ró, a sì ńlókun; - A tún ń dúró ti ara wa. 
- 3. Ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. - Ojú ìgbàgbọ́ la fi ń rí i. - Torí náà, a ó máa pé jọ déédéé - Ká lè máa rìn lọ́nà ìyè. - Títí láé la ó máa sin Jèhófà, - Àwa àti ẹgbẹ́ ará. - Torí náà, ká máa gbéra wa ró - Ká lè jẹ́ adúróṣinṣin. 
(Tún wo Lúùkù 22:32; Ìṣe 14: 21, 22; Gál. 6:2; 1 Tẹs. 5:14.)