ORIN 121
A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn. - Àmọ́ ọkàn wa lè máa fà sí ẹ̀ṣẹ̀. - A gbọ́dọ̀ kóra wa níjàánu, - Ká lè níyè àti àlàáfíà. 
- 2. Ojoojúmọ́ ni Èṣù ń dán wa wò, - Àìpé ara wa sì lè mú wa ṣìnà. - Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń jẹ́ ká borí, - Jèhófà sì tún wà lẹ́yìn wa. 
- 3. Ká máa fọ̀rọ̀ àtìṣe wa yin Jáà, - Ká má ṣe tàbùkù sí orúkọ rẹ̀. - Ká wà láìlẹ́bi lójoojúmọ́, - Ká sì máa kóra wa níjàánu. 
(Tún wo 1 Kọ́r. 9:25; Gál. 5:23; 2 Pét. 1:6.)