ORIN 53
À Ń Múra Láti Lọ Wàásù
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ilẹ̀ mọ́. - A ti ń múra - Láti jáde lọ wàásù. - Àmọ́ òjò ṣú, - Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. - Ó lè dà bíi ká dúró sílé, - ká máa sùn. - (ÈGBÈ)) - Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní, - Ká sì múra sílẹ̀. - Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́; - Yóò gbé wa ró. - Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa, - Jésù ló ń darí wọn. - Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa, - A ó ṣe é yọrí. 
- 2. A ó láyọ̀ - Tí a bá ń fi - Ìmọ̀ràn wọ̀nyí sọ́kàn. - Jèhófà sì ń rí - Gbogbo bá a ṣe ńsapá. - A mọ̀ pé kò ní gbàgbé ìfẹ́ - tá à ń fi hàn. - (ÈGBÈ)) - Èrò tó dáa ló yẹ kí a ní, - Ká sì múra sílẹ̀. - Ká bẹ Jáà pé kó ràn wá lọ́wọ́; - Yóò gbé wa ró. - Àwọn áńgẹ́lì wà lẹ́yìn wa, - Jésù ló ń darí wọn. - Pẹ̀lú ọ̀rẹ́ tòótọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa, - A ó ṣe é yọrí. 
(Tún wo Oníw. 11:4; Mát. 10:5, 7; Lúùkù 10:1; Títù 2:14.)