ORIN 5
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ọlọ́run fagbára rẹ̀ dá mi, - Ó mọ̀ mí gan-an ju bí mo ṣe rò lọ. - Ó sì rí mi nínú ikùn ìyá mi; - Bí a ṣe bí mi, tí mò ń rìn, - tí mò ń sọ̀rọ̀. - Bí mo ṣe ń dìde, tí mò ń jókòó, - Bí mo ṣe ń sùn àti bí mo ṣe ń jí, - Àmọ̀dunjú ni gbogbo rẹ̀ jẹ́ fún ọ; - Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, - màá sì yìn ọ́. - Ìmọ̀ rẹ pọ̀, ó sì kọjá òye mi; - Àgbàyanu ni èyí jẹ́ fún mi. - Bí mo bá sì sá lọ sínú òkùnkùn, - Ìwọ lè fi ẹ̀mí rẹ wá mi rí. - Kò sí ibi tí mo lè sá lọ - Tàbí tí mo lè fara pa mọ́ sí. - Ì báà jẹ́ ‘nú ibojì tàbí òkun - Ibikíbi tí mo bá wà, - o lè rí mi. 
(Tún wo Sm. 66:3; 94:19; Jer. 17:10.)