ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Òótọ́ Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 5
    • Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ṣètò Àwọn Áńgẹ́lì?

      Olú-áńgẹ́lì, ìyẹn Máíkẹ́lì, ni olórí àwọn áńgẹ́lì torí pé òun ni agbára àti àṣẹ rẹ̀ pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àwọn áńgẹ́lì. Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé orúkọ míì tí Jésù Kristi ń jẹ́ ni Máíkẹ́lì.​—1 Tẹsalóníkà 4:16; Júúdà 9.

      Àwọn séráfù wà ní ipò tó ga gan-an láàárín àwọn áńgẹ́lì torí pé wọ́n ní àǹfààní àti iyì tó pọ̀, wọ́n sì máa ń dúró nítòsí ìtẹ́ Ọlọ́run.​—Aísáyà 6:​1-3.

      Àwọn kérúbù náà wà ní ipò gíga, iṣẹ́ pàtàkì ni wọ́n ń ṣe, iṣẹ́ wọn sì kan ipò tí Ọlọ́run wà gẹ́gẹ́ bí Ẹni Gíga Jù Lọ. Bíbélì sábà máa ń sọ pé wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọ́run.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:24; Ìsíkíẹ́lì 9:3; 11:22.

      Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe ìránṣẹ́ fún Ẹni Gíga Jù Lọ, wọ́n sì tún ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.b​—Hébérù 1:​7, 14.

  • Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 5
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?

      Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

      Bíbélì kò kọ́ wa pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa la ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò wá. Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 18:10) Àmọ́, ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé àwọn áńgẹ́lì máa ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn òun, kì í ṣe pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ó. Torí náà, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kì í fẹ̀mí ara wọn wewu, kí wọ́n wá máa ronú pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa dáàbò bo àwọn.

      Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì kì í ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ni? Rárá o. (Sáàmù 91:11) Ó dá àwọn kan lójú gbangba pé Ọlọ́run ti lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn tó sì tún tọ́ wọn sọ́nà. Kenneth, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú wà lára àwọn tó nírú èrò yìí. Àmọ́, a ò lè sọ bóyá bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń rí i pé àwọn áńgẹ́lì ń darí wa bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n, torí pé a ò lè rí àwọn áńgẹ́lì, kò ṣeé ṣe fún wa láti mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n tó láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́. Síbẹ̀, kì í ṣe àṣìṣe rárá tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tó bá ṣe fún wa.​—Kólósè 3:15; Jákọ́bù 1:​17, 18.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́