ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’
    Ilé Ìṣọ́—2012 | May 1
    • ‘Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ!’

      Àpéjọ Àgbègbè Ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

      ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ FRIDAY

      “Ní Ti Jèhófà, Ó Ń Wo Ohun Tí Ọkàn-Àyà Jẹ́”​—1 SÁMÚẸ́LÌ 16:7.

      ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SATURDAY

      “Lára Ọ̀pọ̀ Yanturu Tí Ń Bẹ Nínú Ọkàn-Àyà Ni Ẹnu Ń Sọ”​ —MÁTÍÙ 12:34.

      ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ ỌJỌ́ SUNDAY

      “Fi Ọkàn-Àyà Pípé Pérépéré Sin Jèhófà”​—1 KÍRÓNÍKÀ 28:9.

      Ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ìgbà tí Bíbélì sọ nípa ọkàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, Ìwé Mímọ́ máa ń sọ nípa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa ọkàn téèyàn lè fojú rí. Kí ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ? Ó lè tọ́ka sí ohun tí ẹni kan jẹ́ ní inú, ìyẹn ohun tí ẹnì kan ń rò, bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ohun tó fẹ́.

      Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa? Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì Ọba láti sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Bí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ṣe rí máa ń nípa lórí irú ìgbésí ayé tí à ń gbé nísinsìnyí àti lórí bí a ṣe máa rí ìyè lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Ọlọ́run rí ohun tó wà nínú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Irú èèyàn tá a jẹ́ ní inú, ìyẹn “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ló máa pinnu ojú tí Ọlọ́run máa fi wò wá.—1 Pétérù 3:4.

      Báwo la ṣe lè máa ṣọ́ ọkàn wa? A má dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó yéni yékéyéké ní àwọn àpéjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe kárí ayé, tó máa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù yìí. A pè ọ́ tayọ̀tayọ̀ láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọ yìí.a Ohun tó o máa kọ́ níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa hùwà lọ́nà tí yóò máa mú ọkàn Jèhófà Ọlọ́run yọ̀.—Òwe 27:11.

  • Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Wá Ẹ Wá?
    Ilé Ìṣọ́—2012 | May 1
    • Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Wá Ẹ Wá?

      Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ohun àgbàyanu tó fẹ́ ṣe fún aráyé lè fún ọ láyọ̀. Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i tàbí tó o fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kàn sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ìkànnì wa, ìyẹn, www.watchtower.org.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́