-
Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 4
Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀
Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Kéènì lorúkọ ọmọ tí wọ́n kọ́kọ́ bí, iṣẹ́ àgbẹ̀ ló ń ṣe. Ébẹ́lì lọmọ wọn kejì, àgùntàn lòun máa ń bójú tó ní tiẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, àwọn méjèèjì rú ẹbọ sí Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tíyẹn túmọ̀ sí? Ńṣe ni wọ́n fún Jèhófà ní ẹ̀bùn pàtàkì. Inú Jèhófà dùn sí ẹbọ Ébẹ́lì, àmọ́ inú rẹ̀ kò dùn sí ẹbọ Kéènì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bí Kéènì nínú gan-an. Jèhófà wá kìlọ̀ fún Kéènì pé inú tó ń bí i lè mú kó ṣe nǹkan tó burú. Àmọ́, Kéènì kò gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu.
Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Kéènì ṣe? Ó sọ fún Ébẹ́lì àbúrò ẹ̀ pé: ‘Jẹ́ ká jọ lọ sí oko.’ Nígbà tí wọ́n dénú oko, Kéènì fi nǹkan lu àbúrò ẹ̀, ó sì pa á. Kí lo rò pé Jèhófà máa ṣe? Jèhófà fìyà jẹ Kéènì, ó lé e jìnnà sílé. Kéènì ò lè pa dà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí ẹ̀ mọ́.
Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ ẹ? O lè máa bínú tí nǹkan ò bá rí bó o ṣe fẹ́. Bóyá o máa ń bínú gan-an débi pé àwọn èèyàn ti ń kìlọ̀ fún ẹ. Á dáa kó o tètè wá nǹkan ṣe, kó o sì yíwà pa dà. Ìdí ni pé tó ò bá tètè wá nǹkan ṣe, ìbínú lè mú kó o hùwà burúkú.
Ébẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì níwà tó dáa, ìdí nìyẹn tí Jèhófà ò fi ní gbàgbé ẹ̀ láé. Jèhófà máa jí Ébẹ́lì dìde nígbà tí ayé bá di Párádísè.
“Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:24
-
-
Nóà Kan ÁàkìÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́5
Nóà Kan Áàkì
Nígbà tó yá, àwọn èèyàn pọ̀ gan-an láyé. Àmọ́ ìwà tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ń hù ò dáa rárá. Kódà, àwọn áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú. Wọ́n fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ayé. Ṣé o mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ ṣe bí àwa èèyàn, kí wọ́n sì fẹ́ ìyàwó.
Àwọn áńgẹ́lì yẹn fún àwọn ìyàwó wọn lóyún, wọ́n sì bí àwọn ọmọkùnrin. Nígbà táwọn ọmọ yẹn dàgbà, wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Wọ́n tún máa ń ṣèkà fáwọn èèyàn. Inú Jèhófà ò dùn sí ìwà búburú yẹn. Torí náà, Jèhófà pinnu pé òun máa fi omi tó pọ̀ gan-an pa àwọn èèyàn náà run.
Àmọ́, ọkùnrin kan wà tí kò bá wọn lọ́wọ́ sí ìwà búburú. Nóà lorúkọ ẹ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Òun àti ìyàwó ẹ̀ bí ọmọkùnrin mẹ́ta, orúkọ àwọn ọmọ náà ni, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyàwó kan. Jèhófà sọ fún Nóà pé kó kan áàkì kan kí òun àti ìdílé ẹ̀ lè wà nínú ẹ̀ nígbà tí òjò ńlá náà bá ń rọ̀. Áàkì náà dà bí àpótí tó tóbi gan-an, àmọ́ tó lè dúró sórí omi. Jèhófà tún sọ fún Nóà pé kó kó àwọn ẹranko sínú áàkì náà, káwọn ẹranko náà má bàa kú sínú òjò ńlá tó máa rọ̀ yẹn.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jèhófà bá Nóà sọ̀rọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kan áàkì náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta (50) ọdún tí Nóà àti ìdílé ẹ̀ fi kan áàkì yẹn. Bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n ṣe é náà ni wọ́n ṣe é. Yàtọ̀ síyẹn, Nóà tún máa ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa òjò ńlá tó fẹ́ rọ̀ yẹn. Àmọ́, wọn ò gbọ́rọ̀ sí Nóà lẹ́nu.
Nígbà tó yá, Ọlọ́run ní kí wọ́n wọnú áàkì náà. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Orí tó kàn máa ṣàlàyé.
“Bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín.”—Mátíù 24:37
-