-
Ábúráhámù àti Sérà Ṣègbọràn sí Ọlọ́runÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 8
Ábúráhámù àti Sérà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
Ìlú kan wà tí kò jìnnà sí Bábélì, orúkọ ìlú yẹn ni Úrì. Òrìṣà làwọn ará ìlú yìí ń bọ, àmọ́ ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó ń sin Jèhófà. Orúkọ ọkùnrin náà ni Ábúráhámù.
Lọ́jọ́ kan, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Kúrò nílùú yìí, kó o sì fi àwọn èèyàn ẹ sílẹ̀, kó o lọ máa gbé nílẹ̀ kan tí màá fi hàn ẹ́.’ Jèhófà wá ṣèlérí fún un pé: ‘Màá sọ ẹ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, màá tún ṣe àwọn nǹkan dáadáa fáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé nítorí tìẹ.’
Ábúráhámù ò mọ ibi tí Jèhófà fẹ́ kó lọ, àmọ́ ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Torí náà, Ábúráhámù ṣègbọràn, òun àti Sérà ìyàwó ẹ̀ pẹ̀lú Térà bàbá ẹ̀ àti Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n ẹ̀ kó gbogbo ẹrù wọn, wọ́n sì forí lé ibi tó jìnnà gan-an tí Jèhófà sọ pé òun máa fi hàn wọ́n.
Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Ábúráhámù nígbà tóun àti ìdílé ẹ̀ dé ibi tí Jèhófà ní kí wọ́n lọ. Orúkọ ibẹ̀ ni Kénáánì. Ìlú yẹn ni wọ́n wà nígbà tí Ọlọ́run tún bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tó sì ṣèlérí fún un pé: ‘Ṣé o rí gbogbo ìlú yìí, àwọn ọmọ rẹ ni màá fún.’ Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ábúráhámù àti Sérà ò tíì bímọ lásìkò tí Jèhófà ṣèlérí yẹn? Torí náà, báwo ni Jèhófà ṣe máa mú kí ọmọ wọn jogún ilẹ̀ náà?
“Ìgbàgbọ́ mú kí Ábúráhámù ṣègbọràn . . . ó lọ sí ibì kan tó máa gbà, tó sì máa jogún; ó jáde lọ, bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.”—Hébérù 11:8
-
-
Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 9
Sérà Bímọ Nígbà Tó Darúgbó!
Ọjọ́ pẹ́ tí Ábúráhámù àti Sérà ti jẹ́ tọkọtaya. Ní ìlú Úrì tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀, àwọn nǹkan tó lẹ́wà wà nílé wọn, àmọ́ ní báyìí, inú àgọ́ ni wọ́n ń gbé. Síbẹ̀, Sérà kò ráhùn, ìdí sì ni pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Ó wu Sérà gan-an pé kóun náà bímọ. Lọ́jọ́ kan, ó sọ fún ọkọ ẹ̀ pé: ‘Màá fún ẹ ní Hágárì ìránṣẹ́ mi kó o fi ṣe ìyàwó, tó bá sì bímọ, màá tọ́jú ọmọ náà bíi pé ọmọ mi ni.’ Nígbà tó yá, Hágárì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Orúkọ ọmọ náà ni Íṣímáẹ́lì.
Lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn àlejò mẹ́ta kan wá sílé wọn. Nígbà yẹn, Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) Sérà sì jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún (89). Ábúráhámù ní kí wọ́n wá sinmi díẹ̀ lábẹ́ igi kí wọ́n sì jẹun. Ǹjẹ́ o mọ àwọn àlejò tó wá sílé wọn? Àwọn áńgẹ́lì ni! Wọ́n sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Ní àsìkò yìí lọ́dún tó ń bọ̀, Sérà ìyàwó ẹ máa bí ọmọkùnrin fún ẹ.’ Sérà ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ nínú àgọ́ tó wà. Ó rọra rẹ́rìn-ín, ó sì sọ nínú ọkàn ẹ̀ pé: ‘Ṣé èmi arúgbó yìí tún lè bímọ ṣá?’
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì Jèhófà ṣẹ, Sérà bí ọmọkùnrin kan. Ábúráhámù sọ ọmọ náà ní Ísákì. Ìtumọ̀ orúkọ ọmọ náà ni “Ẹ̀rín.”
Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ísákì jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún (5). Sérà kíyè sí i pé Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́. Torí pé Sérà fẹ́ dáàbò bo Ísákì, ó lọ bá ọkọ ẹ̀, ó sì sọ fún un pé kó lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ. Ábúráhámù ò kọ́kọ́ gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Tẹ́tí sí ohun tí Sérà sọ. Màá tọ́jú Íṣímáẹ́lì. Àmọ́, nípasẹ̀ Ísákì ni màá gbà mú àwọn ìlérí mi ṣẹ.’
“Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ, . . . torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.”—Hébérù 11:11
-