ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ń sá kúrò ní Sódómù, àmọ́ ìyàwó Lọ́ọ̀tì bojú wẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀

      Ẹ̀KỌ́ 10

      Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì

      Ọ̀dọ̀ Ábúráhámù tó jẹ́ àbúrò bàbá Lọ́ọ̀tì ni Lọ́ọ̀tì ń gbé nílẹ̀ Kénáánì. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹran ọ̀sìn Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì pọ̀ gan-an débi pé ibi tí wọ́n ń gbé ò gbà wọ́n mọ́. Ábúráhámù wá sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: ‘A ò ní lè jọ máa gbé pa pọ̀ mọ́. Torí náà, jọ̀ọ́ yan apá ibi tó wù ẹ́ láti lọ, kémi náà sì lọ síbòmíì.’ Ṣé ohun tí Ábúráhámù ṣe yẹn dáa àbí kò dáa?

      Lọ́ọ̀tì rí apá ibì kan ní ilẹ̀ náà tó dáa gan-an, ibẹ̀ ò jìnnà sí ìlú Sódómù. Koríko táwọn ẹran lè jẹ pọ̀ níbẹ̀, omi sì wà níbẹ̀ dáadáa. Bí òun àti ìdílé ẹ̀ ṣe kó lọ síbẹ̀ nìyẹn.

      Ìwà àwọn èèyàn ìlú Sódómù àti Gòmórà tó wà nítòsí rẹ̀ burú gan-an. Kódà ìwà wọn burú débi pé Jèhófà sọ pé òun máa pa àwọn ìlú náà run. Àmọ́, Jèhófà fẹ́ gba Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ là, torí náà ó rán áńgẹ́lì méjì pé kí wọ́n lọ kìlọ̀ fún wọn. Àwọn áńgẹ́lì yẹn sọ fún wọn pé: ‘Ó yá, ẹ ṣe kíá! Ẹ jáde kúrò nílùú yìí torí Jèhófà máa tó pa ìlú yìí run.’

      Àmọ́ Lọ́ọ̀tì kò tètè dá wọn lóhùn. Ṣé o mọ ohun táwọn áńgẹ́lì yẹn ṣe? Wọ́n fa Lọ́ọ̀tì, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì lọ́wọ́, wọ́n sì mú wọn jáde kúrò nílùú náà. Wọ́n wá sọ fún wọn pé: ‘Ó yá! Ẹ máa sá lọ, ẹ má wẹ̀yìn o. Tẹ́ ẹ bá wẹ̀yìn, ikú ni o!’

      Òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà

      Nígbà tí wọ́n dé ìlú kan tó ń jẹ́ Sóárì, Jèhófà rọ òjò iná àti imí ọjọ́ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Ìlú méjèèjì yẹn jóná pátápátá. Ìyàwó Lọ́ọ̀tì ṣe ohun tí Jèhófà ní wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe, ó bojú wẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀! Àmọ́ Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin ẹ̀ kò kú torí pé wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà. Ó dájú pé inú wọn ò ní dùn pé màmá wọn ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Àmọ́ inú wọn á dùn pé àwọn ṣe ohun tí Jèhófà sọ.

      “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.”​—Lúùkù 17:32

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jèhófà fi pa Sódómù àti Gòmórà run? Kí ló fà á tí ìyàwó Lọ́ọ̀tì fi di ọwọ̀n iyọ̀?

      Jẹ́nẹ́sísì 13:1-13; 19:1-26; Lúùkù 17:28, 29, 32; 2 Pétérù 2:6-9

  • Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Ábúráhámù àti Ísákì ń rìn lọ sí Moráyà

      Ẹ̀KỌ́ 11

      Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

      Torí pé Ábúráhámù kọ́ Ísákì ọmọ ẹ̀ dáadáa, ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì gba gbogbo ìlérí Jèhófà gbọ́. Àmọ́ nígbà tí Ísákì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ohun kan tó ṣòro ṣe. Ǹjẹ́ o mọ ohun náà?

      Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tó o ní, kẹ́ ẹ jọ lọ sórí òkè kan nílẹ̀ Moráyà kó o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Ábúráhámù ò mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ.

      Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ méjì rin ìrìn àjò lọ sí Moráyà. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n dé ìtòsí ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n sì ń wo òkè náà níwájú. Ábúráhámù sọ fáwọn ìránṣẹ́ náà pé kí wọ́n dúró de àwọn, òun àti Ísákì sì lọ láti rúbọ. Ábúráhámù ní kí Ísákì ru igi tí wọ́n máa lò, Ábúráhámù sì mú ọ̀bẹ lọ́wọ́. Ísákì béèrè lọ́wọ́ bàbá ẹ̀ pé: ‘Ẹran tá a máa fi rúbọ dà?’ Bàbá ẹ̀ sì dáhùn pé: ‘Ọmọ mi, Jèhófà máa fún wa ni ẹran tá a máa lò.’

      Nígbà tí wọ́n dé orí òkè náà, wọ́n ṣe pẹpẹ kan. Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fi okùn di ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Ísákì, ó sì gbé e sórí pẹpẹ náà.

      Ábúráhámù so Ísákì sórí pẹpẹ, Ábúráhámù sì di ọ̀bẹ mú

      Ábúráhámù wá mú ọ̀bẹ láti pa ọmọ rẹ̀. Ṣàdédé ló gbọ́ ohùn áńgẹ́lì Jèhófà láti ọ̀run, tó sọ pé: ‘Ábúráhámù! Má fọwọ́ kan ọmọ yẹn! Mo ti wá mọ̀ báyìí pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó o fi ṣe tán láti fi ọmọ ẹ rúbọ.’ Ìgbà yẹn ni Ábúráhámù rí àgbò kan tí ìwo ẹ̀ há sínú igbó. Kíá ló tú Ísákì sílẹ̀, tó sì fi àgbò náà rúbọ dípò ẹ̀.

      Láti ọjọ́ yẹn lọ ni Jèhófà ti ń pe Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ òun. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń pè é bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní kí Ábúráhámù ṣe ló máa ń ṣe, nígbà míì ó tiẹ̀ lè má mọ ìdí tí Jèhófà fi ní kóun ṣe nǹkan náà.

      Ábúráhámù tú Ísákì sílẹ̀

      Jèhófà tún wá ṣèlérí fún Ábúráhámù bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Màá bù kún ẹ, màá mú káwọn ọmọ ẹ pọ̀ gan-an.’ Èyí túmọ̀ sí pé ipasẹ̀ ìdílé Ábúráhámù ni Jèhófà máa gbà bù kún gbogbo èèyàn rere.

      “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòhánù 3:16

      Ìbéèrè: Kí ni Ábúráhámù ṣe tó fi hàn pé ó gba Jèhófà gbọ́? Kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún Ábúráhámù?

      Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18; Hébérù 11:17-19; Jémíìsì 2:21-23

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́