ORIN 31
Bá Ọlọ́run Rìn!
Bíi Ti Orí Ìwé
	(Míkà 6:8)
- 1. Fìrẹ̀lẹ̀ bá Ọlọ́run rìn; - Sún mọ́ ọn, kó o sì gbára lé e. - Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, - Ó sì máa fún ẹ lókun. - Tó o bá rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, - Kò ní jẹ́ kó o ṣìnà. - Tó o bá ń ṣègbọràn s’Ọ́lọ́run, - Á tọ́ ẹ sọ́nà ìyè. 
- 2. Fìwà mímọ́ b’Ọ́lọ́run rìn; - Fọkàn sí ohun mímọ́. - Kò sí bí àdánwò ṣe fẹ́ le tó, - Yóò jẹ́ kó o lè fara dàá. - Ohunkóhun tó yẹ fún ìyìn, - Tó sì jẹ́ òtítọ́ - Ni kó o máa rò nígbà gbogbo; - Jáà yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. 
- 3. Fi ayọ̀ bá Ọlọ́run rìn; - Máa yọ̀ pó o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀. - Dúpẹ́ fún gbogbo ẹ̀bùn tó fún ọ - Àti bó ṣe ń bù kún ọ. - Bóo ṣe ń bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn, - Máa fayọ̀ kọrin sí i. - Èyí yóò jẹ́ káráyé mọ̀ - Pé Jèhófà lò ń bá rìn. 
(Tún wo Jẹ́n. 5:24; 6:9; Fílí. 4:8; 1 Tím. 6:6-8.)