ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ta Ni Jóòbù?
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Ééwo kún gbogbo ara Jóòbù, àwọn ọkùnrin mẹ́ta sì wá rí i

      Ẹ̀KỌ́ 16

      Ta Ni Jóòbù?

      Ọkùnrin kan wà tó ń gbé nílẹ̀ Úsì tó sì ń jọ́sìn Jèhófà. Jóòbù lorúkọ ẹ̀. Ọkùnrin yẹn lówó gan-an, ó sì ní àwọn ọmọ àtàwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó máa ń ṣoore fáwọn tálákà, ó sì tún máa ń ṣoore fáwọn tí ọkọ wọn ti kú àtàwọn ọmọ tí kò lóbìí. Àmọ́, ṣé bí Jóòbù ṣe ń ṣoore yẹn wá sọ pé kò ní níṣòro kankan?

      Sátánì Èṣù

      Èṣù ń ṣọ́ Jóòbù, àmọ́ Jóòbù ò mọ̀ pé ó ń ṣọ́ òun. Jèhófà sọ fún Sátánì pé: ‘Ǹjẹ́ o kíyè sí Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sẹ́ni tó dà bíi rẹ̀ láyé. Ó máa ń tẹ́tí sí mi, ó sì máa ń hùwà rere.’ Sátánì dáhùn pé: ‘Mo gbà pé Jóòbù máa ń ṣe ohun tó o fẹ́. Ò ń dáàbò bò ó, o sì ń bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ó nílé, ó ní ilẹ̀, ó sì láwọn ẹran tó pọ̀. Tó o bá gba gbogbo ẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀, wàá rí i pé kò ní sìn ẹ́ mọ́.’ Jèhófà wá sọ pé: ‘O lè lọ dán Jóòbù wò. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ pa á.’ Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà kí Sátánì dán Jóòbù wò? Ó dá Jèhófà lójú pé Jóòbù máa jẹ́ olóòótọ́.

      Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìdààmú bá Jóòbù. Lákọ̀ọ́kọ́, ó rán àwọn Sábéà pé kí wọ́n jí àwọn màlúù àtàwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Jóòbù. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi iná jó gbogbo àgùntàn Jóòbù. Nígbà tó yá, àwọn ará Kálídíà wá jí àwọn ràkúnmí ẹ̀. Wọ́n tún pa àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ tó ń tọ́jú àwọn ẹranko yẹn. Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tó burú jù tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù? Lọ́jọ́ kan táwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ń ṣe àríyá, ilé wó pa gbogbo wọn. Inú Jóòbù bà jẹ́ gan-an, àmọ́ kò fi Jèhófà sílẹ̀.

      Síbẹ̀, Sátánì ò fi Jóòbù sílẹ̀. Ó tún mú kí àìsàn ṣe Jóòbù, tó fi jẹ́ pé ééwo wà ní gbogbo ara ẹ̀, ara sì máa ń ro ó. Jóòbù ò mọ ìdí tí gbogbo nǹkan yẹn fi ń ṣẹlẹ̀ sóun. Síbẹ̀, Jóòbù ò fi Jèhófà sílẹ̀, ó ṣì ń jọ́sìn ẹ̀. Inú Ọlọ́run dùn sí Jóòbù gan-an.

      Nígbà tó yá, Sátánì rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta láti lọ dán Jóòbù wò. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ó dájú pé o ti dẹ́ṣẹ̀, tó ò sì jẹ́wọ́. Torí ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe ń fìyà jẹ ọ́.’ Jóòbù sọ pé: ‘Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, mi ò dẹ́ṣẹ̀ kankan.’ Àmọ́, Jóòbù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà ló fa ìṣòro tóun ní, ó tún sọ pé Ọlọ́run ò ṣe dáadáa sóun.

      Ọ̀dọ́kùnrin kan wà níbẹ̀ tó ń jẹ́ Élíhù. Ó ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà táwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ó wá dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó ní: ‘Ọ̀rọ̀ tí gbogbo yín sọ ò dáa. Jèhófà tóbi ju gbogbo wa lọ, kì í ṣe búburú rárá. Ó ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.’

      Jóòbù àti ìyàwó ẹ̀ gbé ọmọ ìkókó kan dání

      Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà wá bá Jóòbù sọ̀rọ̀. Ó sọ pé: ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ọ̀run àtayé? Kí ló dé tó o fi sọ pé mi ò ṣe dáadáa sí ẹ? Ò ń sọ̀rọ̀, àmọ́ o ò mọ ìdí táwọn nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀.’ Jóòbù gbà pé òun ṣàṣìṣe, ó sì sọ pé: ‘Jọ̀ọ́, má bínú. Tẹ́lẹ̀, ṣe ni mo gbọ́ nípa rẹ, àmọ́ mo ti wá mọ̀ ẹ́ báyìí. Kò sóhun tí ìwọ Ọlọ́run ò lè ṣe. Jọ̀ọ́, dárí jì mí fún gbogbo ohun tí mo ti sọ.’

      Nígbà tó yá, Jóòbù bọ́ nínú ìṣoro yẹn, Jèhófà mú kí ara ẹ̀ yá, ó sì mú kó ní nǹkan tó pọ̀ ju ohun tó ní tẹ́lẹ̀ lọ. Jóòbù pẹ́ láyé gan-an, ó sì gbádùn ayé ẹ̀. Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà lásìkò tí nǹkan le. Ṣé wàá ṣe bíi Jóòbù, kó o sì ṣe ìfẹ́ Jèhófà kódà nígbà ìṣòro?

      “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà jẹ́ kó yọrí sí.”​—Jémíìsì 5:11

      Ìbéèrè: Báwo ni Sátánì ṣe dán Jóòbù wò? Kí ni Jèhófà ṣe fún Jóòbù?

      Jóòbù 1:1–3:26; 4:7; 32:1-5; 34:5, 21; 35:2; 36:15, 26; 38:1-7; 40:8; 42:1-17

  • Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Míríámù ń yọjú nítòsí nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò rí Mósè

      Ẹ̀KỌ́ 17

      Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

      Ìdílé Jékọ́bù túbọ̀ ń pọ̀ sí i nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn la wá mọ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù àti Jósẹ́fù kú, Fáráò míì di ọba nílẹ̀ Íjíbítì. Ẹ̀rù ń ba ọba yẹn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i àti pé ọwọ́ àwọn ará Íjíbítì ò ní lè ká wọn. Torí náà, Fáráò sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú. Ó wá fipá mú wọn pé kí wọ́n máa ṣe búlọ́ọ̀kù, kí wọ́n sì tún máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó le. Àmọ́ bí àwọn ará Íjíbítì ṣe ń fipá mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i. Inú Fáráò ò dùn pé wọ́n ń pọ̀ sí i, torí náà ó pàṣẹ pé tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá bí ọmọkùnrin, kí wọ́n pa ọmọ náà. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé ọkàn wọn máa balẹ̀?

      Obìnrin kan wà tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, Jókébédì lorúkọ ẹ̀. Nígbà tí obìnrin yẹn bí ọmọkùnrin kan, kò fẹ́ kí wọ́n pa ọmọ náà, ó wá gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ó sì gbé e pa mọ́ sáàárín àwọn koríko tó wà létí Odò Náílì. Míríámù tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà dúró sítòsí kó bàa lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

      Ọmọbìnrin Ọba Fáráò wá wẹ̀ lódò yẹn, ó sì rí apẹ̀rẹ̀ náà. Nígbà tó ṣí i, ó rí i tí ọmọ náà ń sunkún, àánú ẹ̀ sì ṣe é. Míríámù ẹ̀gbọ́n ọmọ jòjòló náà wá béèrè pé: ‘Ṣé kí n bá yín wá obìnrin kan tó máa bá yín tọ́jú ọmọ náà?’ Nígbà tí ọmọ ọba yẹn sọ pé kí Míríámù ṣe bẹ́ẹ̀, ó lọ pe Jókébédì màmá wọn. Ọmọbìnrin Fáráò wá sọ fún Jókébédì pé: ‘Gbé ọmọ yìí, bá mi tọ́jú ẹ̀, màá sanwó fún ẹ.’

      Mósè ń sá lọ

      Nígbà tí ọmọ kékeré náà dàgbà, Jókébédì mú un lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Fáráò. Obìnrin yẹn wá gbà á ṣọmọ. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú ẹ̀, ó sì pe orúkọ ẹ̀ ní Mósè. Inú ilé ọba ni Mósè dàgbà sí, kò sì sóhun tó fẹ́ tí wọn ò ní lè ṣe fún un. Àmọ́ Mósè ò gbàgbé Jèhófà. Ó mọ̀ pé òun kì í ṣe ọmọ Íjíbítì, pé ọmọ Ísírẹ́lì lòun. Torí náà, ó pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn.

      Nígbà tí Mósè pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó pinnu pé òun máa ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. Inú Mósè ò dùn nígbà tó rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu ọmọ Ísírẹ́lì kan. Torí bẹ́ẹ̀, ó lu ọmọ Íjíbítì náà pa, ó wá fi erùpẹ̀ bo òkú rẹ̀ mọ́lẹ̀. Nígbà tí Fáráò gbọ́ ohun tí Mósè ṣe, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè. Àmọ́ Mósè sá lọ sílẹ̀ Mídíánì. Jèhófà rí Mósè níbi tó wà, ó sì tọ́jú ẹ̀.

      “Ìgbàgbọ́ mú kí Mósè kọ̀ kí wọ́n máa pe òun ní ọmọ ọmọbìnrin Fáráò . . . ó yàn pé kí wọ́n fìyà jẹ òun pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run.”​—Hébérù 11:24, 25

      Ìbéèrè: Báwo làwọn ará Íjíbítì ṣe ń ṣe sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Kí nìdí tí Mósè fi sá kúrò ní Íjíbítì?

      Jẹ́nẹ́sísì 49:33; Ẹ́kísódù 1:1-14, 22; 2:1-15; Ìṣe 7:17-29; Hébérù 11:23-27

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́