ORIN 124
Jẹ́ Adúróṣinṣin
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Dúró ṣinṣin sí Jèhófà, - Kó o sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. - A ti yara wa sí mímọ́; - Àṣẹ rẹ̀ la fẹ́ pa mọ́. - Tá a bá ń ṣègbọràn sọ́rọ̀ rẹ̀, - Ó máa ṣe wá láǹfààní. - Ká gbẹ́kẹ̀ lé e; olóòótọ́ ni. - Má ṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 
- 2. Dúró ṣinṣin sáwọn ará - Ní àkókò ìṣòro. - Ká máa kẹ́ wọn, ká gbé wọn ró, - Ká sì sọ̀rọ̀ tó tura. - Ká máa bọlá fáwọn ará; - Bọ̀wọ̀ fún wọn látọkàn. - Ká rí i pé à ń dúró tì wọ́n; - Ká má fi wọ́n sílẹ̀ láé. 
- 3. Dúró ṣinṣin, gba ìmọ̀ràn - Àwọn tó ń múpò ‘wájú - Tí wọ́n bá ti ń tọ́ wa sọ́nà; - Ká gbọ́ràn tọkàntọkàn. - Jèhófà yóò sì bù kún wa, - Yóò sọ wá d’alágbára. - Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, - Ti Jèhófà la ó máa jẹ́. 
(Tún wo Sm. 149:1; 1 Tím. 2:8; Héb. 13:17.)