ORIN 47
Máa Gbàdúrà sí Jèhófà Lójoojúmọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Gbàdúrà sí Jáà, ó ń gbọ́ àdúrà. - Àǹfààní ló jẹ́ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀. - Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ. - O lè fọkàn tán an, ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni. - Gbàdúrà lójoojúmọ́. 
- 2. Gbàdúrà sí Jáà, dúpẹ́ ẹ̀mí rẹ. - Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, tọrọ ‘dáríjì; - Kí ìwọ náà sì máa dárí jini. - Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pérùpẹ̀ ni wá. - Gbàdúrà lójoojúmọ́. 
- 3. Gbàdúrà sí Jáà tíṣòro bá dé. - Bàbá wa ló jẹ́, kò jìnnà sí wa. - Wá ìrànlọ́wọ́ àti ààbò rẹ̀. - Má bẹ̀rù rárá, o lè gbẹ́kẹ̀ lé e. - Gbàdúrà lójoojúmọ́. 
(Tún wo Sm. 65:5; Mát. 6:9-13; 26:41; Lúùkù 18:1.)