ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Bárákì sọ fún Dèbórà pé kó tẹ̀ lé òun

      Ẹ̀KỌ́ 32

      Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì

      Jóṣúà darí àwọn èèyàn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sì kú lẹ́ni àádọ́fà (110) ọdún. Jèhófà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jọ́sìn ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà. Àmọ́ lẹ́yìn tó kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà bíi tàwọn ọmọ Kénáánì. Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò sin Jèhófà mọ́, Jèhófà gbà kí Jábínì ọba Kénáánì fìyà jẹ wọ́n. Àmọ́ wọ́n bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà yan Bárákì láti jẹ́ aṣáájú wọn. Òun ló máa ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

      Dèbórà tó jẹ́ wòlíì obìnrin wá ránṣẹ́ sí Bárákì. Ó fẹ́ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an fún Bárákì. Ó ní: ‘Mú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin, kó o sì lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Jábínì létí odò Kíṣónì. Ibẹ̀ lo ti máa ṣẹ́gun Sísérà, tó jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun Jábínì.’ Bárákì sọ fún Dèbórà pé òun máa lọ tí Dèbórà bá máa tẹ̀ lé òun. Dèbórà wá dáhùn pé: ‘Màá tẹ̀ lé ẹ lọ. Àmọ́, jẹ́ kó yé ẹ pé ìwọ kọ́ lo máa pa Sísérà. Jèhófà ti sọ pé obìnrin ló máa pa á.’

      Dèbórà tẹ̀ lé Bárákì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ lọ sórí Òkè Tábórì láti múra sílẹ̀ fún ogun náà. Gbàrà tí Sísérà gbọ́ nípa ẹ̀ ló ti kó kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ àtàwọn ọmọ ogun jọ níbi ẹsẹ̀ òkè náà. Dèbórà sọ fún Bárákì pé: ‘Òní yìí ni Jèhófà máa mú kó o ṣẹ́gun.’ Ni Bárákì àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ ogun ẹ̀ bá sọ̀ kalẹ̀ lọ bá ẹgbẹ́ ogun Sísérà tó jẹ́ alágbára.

      Jèhófà mú kí omi Odò Kíṣónì kún àkúnya. Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà sì rì sínú ẹrẹ̀. Ni Sísérà bá fi kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ sílẹ̀, ó sì sá lọ. Bárákì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Sísérà, àmọ́ wọn ò rí Sísérà pa! Ó wá lọ fara pa mọ́ sínú àgọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Jáẹ́lì. Jáẹ́lì fún un ní wàrà mu, ó sì faṣọ bò ó. Ni Sísérà bá sùn lọ fọnfọn. Jáẹ́lì wá rọra sún mọ́ ọn, ó sì kan ìṣó ńlá mọ́ orí ẹ̀. Bí Sísérà ṣe kú nìyẹn.

      Bárákì àti Dèbórà ń kọrin ìyìn sí Jèhófà

      Nígbà tí Bárákì wá Sísérà débẹ̀, Jáẹ́lì jáde wá bá a látinú àgọ́, ó sì sọ pé: ‘Máa bọ̀. Màá fi ọkùnrin tó ò ń wá hàn ẹ́.’ Bárákì tẹ̀ lé e wọlé, ó sì bá òkú Sísérà nílẹ̀ gbalaja. Bárákì àti Dèbórà wá fi orin yin Ọlọ́run lógo pé ó jẹ́ káwọn ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí ìdààmú kankan fún ogójì (40) ọdún.

      “Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere jẹ́ agbo ọmọ ogun ńlá.”​—Sáàmù 68:11

      Ìbéèrè: Báwo ni Dèbórà ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́? Kí ni Jáẹ́lì ṣe tó fi hàn pé ó nígboyà?

      Àwọn Onídàájọ́ 4:1–5:31

  • Rúùtù àti Náómì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Náómì sọ fún Rúùtù pé kó pa dà sílé

      Ẹ̀KỌ́ 33

      Rúùtù àti Náómì

      Nígbà kan tí kò sí oúnjẹ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Náómì kó lọ sílẹ̀ Móábù. Òun àti ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin ẹ̀ méjì ni wọ́n jọ lọ. Nígbà tó yá, ọkọ Náómì kú. Àwọn ọmọ ẹ̀ sì fẹ́ Rúùtù àti Ópà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Náómì méjèèjì náà kú.

      Nígbà tí Náómì gbọ́ pé oúnjẹ ti wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó pinnu pé òun máa pa dà sílé. Rúùtù àti Ópà sì tẹ̀ lé e, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ, Náómì sọ fún wọn pé: ‘Ìyàwó dáadáa lẹ jẹ́ fáwọn ọmọ mi, ẹ sì ṣe dáadáa sí èmi náà. Mo fẹ́ kẹ́yin méjèèjì tún pa dà lọ́kọ. Torí náà, ẹ pa dà sí Móábù.’ Àwọn obìnrin náà sọ pé: ‘Màmá, a fẹ́ràn yín gan-an! A ò fẹ́ fi yín sílẹ̀.’ Àmọ́, Náómì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n pa dà. Nígbà tó yá, Ópà pa dà, ó sì ku Rúùtù nìkan. Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ópà ti ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹ̀ àti ọlọ́run ẹ̀. Máa tẹ̀ lé e lọ, kó o sì pa dà sílé ìyá ẹ.’ Àmọ́ Rúùtù sọ pé: ‘Mi ò ní pa dà lẹ́yìn yín. Àwọn èèyàn yín á di èèyàn mi, Ọlọ́run yín á sì di Ọlọ́run mi.’ Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Náómì nígbà tí Rúùtù sọ̀rọ̀ yìí?

      Àkókò tí wọ́n ń kórè ọkà báálì ni Rúùtù àti Náómì dé Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, Rúùtù lọ sóko ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì kó lè lọ kó àwọn ọkà tó já bọ́ nígbà tí wọ́n ń kórè. Ọmọ Ráhábù ni Bóásì, ó gbọ́ pé ọmọ ilẹ̀ Móábù ni Rúùtù àti pé fúnra ẹ̀ ló pinnu láti dúró ti ìyá ọkọ ẹ̀. Ó wá sọ fáwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣẹ́ ọkà kù fún Rúùtù kó lè rí kó lọ sílé.

      Rúùtù ń ṣa ọkà lóko Bóásì

      Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Náómì bi Rúùtù pé: ‘Inú oko ta lo ti ṣiṣẹ́ lónìí?’ Rúùtù sọ pé: ‘Oko ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Bóásì ni.’ Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ìbátan ọkọ mi ni Bóásì. Máa ṣiṣẹ́ lóko ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń bá a ṣiṣẹ́. Kò sí nǹkan tó máa ṣe ẹ́.’

      Náómì pẹ̀lú Rúùtù, Bóásì àti Óbédì

      Oko Bóásì ni Rúùtù ti ṣiṣẹ́ títí tí àkókò ìkórè náà fi kọjá. Bóásì kíyè sí i pé Rúùtù ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì ní ìwà tó dáa. Lákòókò yẹn, tí ọkùnrin kan bá kú, tí kò sì ní ọmọkùnrin, ìbátan ẹ̀ ló máa fẹ́ ìyàwó tó fi sílẹ̀. Torí náà, Bóásì fẹ́ Rúùtù. Wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Óbédì. Óbédì ló wá di bàbá bàbá Ọba Dáfídì. Inú àwọn ọ̀rẹ́ Náómì dùn. Wọ́n sọ pé: ‘Jèhófà kọ́kọ́ fún ẹ ní Rúùtù, tó ń tọ́jú ẹ, ní báyìí, ó ti fún ẹ ní ọmọ ọmọ. A yin Jèhófà lógo.’

      “Ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.”​—Òwe 18:24

      Ìbéèrè: Báwo ni Rúùtù ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn Náómì? Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó Rúùtù àti Náómì?

      Rúùtù 1:1–4:22; Mátíù 1:5

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́