-
Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará MídíánìÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 34
Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì
Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì ń bọ òrìṣà. Fún ọdún méje gbáko, àwọn ará Mídíánì máa ń jí ẹran ọ̀sìn wọn, wọ́n sì ń ba irè oko wọn jẹ́. Inú ihò àpáta àti orí òkè làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń sá pa mọ́ sí káwọn ará Mídíánì má bàa rí wọn. Wọ́n wá gbàdúrà pé kí Jèhófà gba àwọn. Torí náà, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gídíónì. Áńgẹ́lì náà sọ pé: ‘Jèhófà ti yàn ẹ́ láti jẹ́ akínkanjú jagunjagun.’ Gídíónì wá béèrè pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa gba Ísírẹ́lì sílẹ̀? Èmi tí mi ò já mọ́ nǹkan kan.’
Báwo ni Gídíónì ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun? Ó mú òwú kan sílẹ̀, ó sì sọ fún Jèhófà pé: ‘Láàárọ̀ ọ̀la, tí ìrì bá sẹ̀ sí òwú yìí nìkan tílẹ̀ sì gbẹ, màá mọ̀ pé lóòótọ́ lo fẹ́ kí n gba Ísírẹ́lì là.’ Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìrì sẹ̀ sí òwú yẹn nìkan, ilẹ̀ sì gbẹ! Àmọ́ Gídíónì tún sọ pé tó bá di ọjọ́ kejì, kí òwú yẹn nìkan gbẹ, àmọ́ kílẹ̀ tutù. Nígbà tíyẹn náà ṣẹlẹ̀, ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà ti yan òun lóòótọ́. Ni Gídíónì bá kó àwọn ọmọ ogun jọ láti bá àwọn ará Mídíánì jà.
Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Màá jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì pọ̀, ẹ lè rò pé ẹ̀yin fúnra yín lẹ ṣẹ́gun. Sọ fun wọn pé kí ẹnikẹ́ni tẹ́rù ń bà pa dà sílé.’ Torí náà, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ọmọ ogun náà pa dà sílé, ó wá ku ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) péré. Jèhófà tún sọ pé: ‘Àwọn ọmọ ogun yìí ṣì pọ̀. Kó wọn lọ sétí odò, kó o sì sọ fún wọn pé kí wọ́n mu omi. Kìkì àwọn tó ń fojú ẹ̀gbẹ́ kan ṣọ́ àwọn ọ̀tá nígbà tí wọ́n ń mu omi ni kó o yàn.’ Ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọmọ ogún péré ló ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà wá ṣèlérí pé ìwọ̀nba àwọn ọmọ ogun yẹn ló máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Mídíánì tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùnléláàádóje (135,000).
Lóru ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún Gídíónì pé: ‘Ó ti tó àkókò báyìí láti lọ bá àwọn ọmọ ogún Mídíánì jà!’ Gídíónì fún àwọn ọmọ ogún ẹ̀ ní ìwo àti ìkòkò ńlá kan tí iná wà nínú ẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa wò mí, kẹ́ ẹ sì ṣe bí mo ti ṣe.’ Gídíónì fọn ìwo ọwọ́ ẹ̀, ó fọ́ ìkòkò náà mọ́lẹ̀, ó fi ìná náà sọ́tùn-ún sósì, ó sì pariwo pé: ‘Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!’ Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ogun Mídíánì, wọ́n wá ń sá káàkiri. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ara wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá.
“Kí agbára tó kọjá ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kó má sì jẹ́ látọ̀dọ̀ wa.”—2 Kọ́ríńtì 4:7
-
-
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní ỌmọkùnrinÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 35
Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin
Ọmọ Ísírẹ́lì kan wà tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ẹlikénà. Ìyàwó méjì ló fẹ́. Hánà àti Pẹ̀nínà lorúkọ wọn, àmọ́ Hánà ló fẹ́ràn jù. Pẹ̀nínà máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé kò rọ́mọ bí, àmọ́ Pẹ̀nínà bímọ tó pọ̀ ní tiẹ̀. Lọ́dọọdún, Ẹlikénà máa ń kó ìdílé ẹ̀ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò kí wọ́n lè lọ jọ́sìn Jèhófà. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n wà ní Ṣílò, ó kíyè sí i pé inú Hánà ìyàwó ẹ̀ ò dùn rárá. Ó wá sọ pé: ‘Hánà jọ̀ọ́ má sunkún mọ́. Bó ò bá tiẹ̀ bímọ, fọkàn balẹ̀. Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ.’
Nígbà tó yá, Hánà lọ dá gbàdúrà. Bó ṣe ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ ló ṣáà ń sunkún. Ó ṣèlérí pé: ‘Jèhófà, tó o bá fún mi ní ọmọkùnrin, ìwọ ni màá fún, ó sì máa fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ sìn ẹ́.’
Élì Àlùfáà Àgbà rí i pé Hánà ń sunkún, ó sì ronú pé ó ti mutí yó. Hánà dáhùn pé: ‘Rárá Olúwa mi, mi ò mutí yó. Mo níṣòro ńlá kan ni, mo sì ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.’ Élì wá rí i pé èrò òun ò dáa, ló bá sọ fún un pé: ‘Kí Ọlọ́run fún ẹ lóhun tó o tọrọ lọ́wọ́ ẹ̀.’ Ara tu Hánà, ó sì bá ọ̀nà ẹ̀ lọ. Kò pé ọdún kan lẹ́yìn náà tó fi bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ ẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Ṣé o mọ bínú Hánà ṣe máa dùn tó?
Hánà ò gbàgbé ìlérí tó ṣe fún Jèhófà. Bí Hánà ṣe rí i pé Sámúẹ́lì ti dàgbà díẹ̀, ó mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn kó lè máa sin Jèhófà níbẹ̀. Ó sọ fún Élì pé: ‘Ọmọkùnrin tí mo tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́run nìyí. Mo ti yọ̀ǹda ẹ̀ fún Jèhófà títí láé.’ Ọdọọdún ni Ẹlikénà àti Hánà máa ń lọ wo Sámúẹ́lì, wọ́n á sì mú aṣọ kékeré tí kò lápá lọ fún un. Jèhófà tún wá fún Hánà ní ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì míì.
“Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí.”—Mátíù 7:7
-