-
Dáfídì àti GòláyátìÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 40
Dáfídì àti Gòláyátì
Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Lọ sí ilé Jésè. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ ló máa di ọba Ísírẹ́lì.’ Torí náà, Sámúẹ́lì lọ sílé Jésè. Nígbà tí Sámúẹ́lì rí àkọ́bí Jésè, ó sọ fún ara ẹ̀ pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin yìí ló máa jẹ́.’ Àmọ́ Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé kì í ṣe òun. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ọkàn èèyàn ni mò ń wò, kì í ṣe béèyàn ṣe rí.’
Jésè wá mú àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ mẹ́fà míì wá sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì. Àmọ́ Sámúẹ́lì sọ fún Jésè pé: ‘Jèhófà ò mú ẹnì kankan lára wọn. Ṣé o ní àwọn ọmọkùnrin míì?’ Jésè dáhùn pé: ‘Ó ṣì ku ọ̀kan, àbúrò gbogbo wọn, Dáfídì lorúkọ ẹ̀. Ó wà níbi tó ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn mi.’ Nígbà tí wọ́n mú Dáfídì dé, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Ẹni tí mo fẹ́ gan-an nìyẹn!’ Sámúẹ́lì da òróró sórí Dáfídì, ó sì yàn án pé òun ló máa di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú.
Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ bá àwọn ará Filísínì jagun. Ọkùnrin kan wà lára àwọn ọmọ ogun Filísínì yẹn tó ga gan-an tó sì lágbára, Gòláyátì lorúkọ ẹ̀. Ojoojúmọ́ ló máa ń fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ rán ẹnì kan sí mi kó wá bá mi jà. Tó bá ṣẹ́gun, a máa di ẹrú yín. Àmọ́ tí mo bá ṣẹ́gun, ẹ máa di ẹrú wa.’
Àsìkò yẹn ni Dáfídì wá síbi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà, ó wá gbé oúnjẹ fáwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ táwọn náà jẹ́ ọmọ ogun. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ ohun tí Gòláyátì ń sọ, ó sọ pé: ‘Màá bá ọkùnrin yẹn jà!’ Ọba Sọ́ọ̀lù sọ fún un pé: ‘Ọmọdé ni ẹ́, àgbàlagbà ni ọkùnrin náà.’ Àmọ́, Dáfídì dá a lóhùn pé: ‘Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́.’
Sọ́ọ̀lù fẹ́ kí Dáfídì wọ ẹ̀wù ogun òun, àmọ́ Dáfídì sọ pé: ‘Mi ò lè wọ ẹ̀wù yìí.’ Dáfídì wá mú rọ́bà tó fi ń ta òkúta, ó sì lọ sétí odò kan. Ó ṣa òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀, ó sì kó wọn sínú àpò tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì wá sáré lọ bá Gòláyátì. Nígbà tí Gòláyátì rí i, ó sọ pé: ‘Máa bọ̀, ìwọ ọmọ kékeré yìí. Tí mo bá pa ẹ́ tán, àwọn ẹyẹ àti ẹranko ló máa jẹ òkú rẹ.’ Dáfídì ò bẹ̀rù. Ó sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Ìwọ mú idà àti ọ̀kọ̀ láti wá bá mi jà, àmọ́ èmi máa bá ẹ jà ní orúkọ Jèhófà. Àwa kọ́ lò ń bá jà, Ọlọ́run lò ń bá jà. Gbogbo àwọn tó wà níbí lónìí ló máa mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju idà àti ọ̀kọ̀ tó o gbé dání lọ. Jèhófà máa fi gbogbo yín lé wa lọ́wọ́.’
Dáfídì wá mú ọ̀kan lára òkúta yẹn sínú rọ́bà ọwọ́ ẹ̀, ó sì fi gbogbo agbára ẹ̀ ta òkúta tó wà nínú rọ́bà náà. Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́, ńṣe ni òkúta yẹn wọ orí Gòláyátì lọ. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Gòláyátì ṣubú lulẹ̀, ó sì kú. Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Filísínì, wọ́n sì sá lọ. Ṣé ìwọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi Dáfídì?
“Lójú èèyàn, kò ṣeé ṣe, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, torí ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Máàkù 10:27
-
-
Dáfídì àti Sọ́ọ̀lùÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 41
Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù
Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, Ọba Sọ́ọ̀lù sọ Dáfídì di ọ̀gá àwọn ọmọ ogun ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dáfídì máa ń lọ jagun tó sì máa ń ṣẹ́gun. Ìyẹn mú káwọn èèyàn gba ti Dáfídì gan-an. Tí Dáfídì bá ti ogun dé, àwọn obìnrin máa ń kọrin fún un, wọ́n á sì máa jó. Wọ́n máa ń kọrin pé: ‘Ẹgbẹ̀rún, ẹgbẹ̀rún ni Sọ́ọ̀lù pa lójú ogun, àmọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá mẹ́wàá ni Dáfídì pa ní tiẹ̀!’ Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa Dáfídì.
Dáfídì mọ bí wọ́n ṣe máa ń fi háàpù kọrin gan-an. Lọ́jọ́ kan tí Dáfídì ń fi háàpù kọrin fún Sọ́ọ̀lù, ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ lu Dáfídì kó lè pa á. Àmọ́ Dáfídì yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà sì gún ògiri. Lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Sọ́ọ̀lù tún wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì sá lọ, ó sì sá pa mọ́ sínú aginjù.
Ni Sọ́ọ̀lù bá kó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àwọn ọmọ ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá Dáfídì kiri. Sọ́ọ̀lù wọ inú ihò kan tó wà nínú àpáta, inú ihò yẹn sì ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ sá pa mọ́ sí. Àwọn ọmọ ogun Dáfídì sọ fún Dáfídì pé: ‘Wò ó, ọwọ́ ẹ ti ba Sọ́ọ̀lù báyìí.’ Dáfídì wá rọra lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sì gé díẹ̀ lára aṣọ tó wọ̀. Sọ́ọ̀lù ò tiẹ̀ mọ̀ rárá. Àmọ́, inú Dáfídì ò dùn pé òun gé aṣọ Sọ́ọ̀lù torí ó gbà pé ńṣe nìyẹn fi hàn pé òun ò bọ̀wọ̀ fún ọba tí Jèhófà yàn. Torí náà, kò jẹ́ káwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa Sọ́ọ̀lù. Dáfídì wá pe Sọ́ọ̀lù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò bá ti pa á, àmọ́ òun ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé Sọ́ọ̀lù máa yíwà pa dà, tó sì máa dẹ̀yìn lẹ́yìn Dáfídì?
Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ńṣe ni Sọ́ọ̀lù tún ń wá bó ṣe máa pa Dáfídì. Lóru ọjọ́ kan, Dáfídì àti Ábíṣáì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Dáfídì rọra yọ́ lọ síbi tí Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ wà. Ábínérì tó máa ń ṣọ́ ọba pàápàá ti sùn. Ábíṣáì wá sọ pé: ‘Ọwọ́ tẹ Sọ́ọ̀lù! Jẹ́ kí n pa á dà nù.’ Àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé: ‘Jèhófà máa jẹ Sọ́ọ̀lù níyà. Jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ká sì gbé ìkòkò omi ẹ̀, ká máa lọ.’
Dáfídì wá gun orí òkè kan tó wà nítòsí, ó ń wo Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ láti ibẹ̀. Ó wá ké sí Ábínérì pé: ‘Ábínérì, kí ló dé tó ò ṣe iṣẹ́ ẹ bí iṣẹ́, ṣebí ọba ló yẹ kó o máa ṣọ́? Ó dáa, ọ̀kọ̀ àti ìkòkò omi ọba dà?’ Sọ́ọ̀lù dá ohùn Dáfídì mọ̀, ó wá sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé o fẹ́ pa mí ni, wàá ti pa mí, àmọ́ o ò ṣe bẹ́ẹ̀. Mo gbà pé ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì lẹ́yìn mi.’ Bí Sọ́ọ̀lù ṣe pa dà sáàfin ẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ẹbí Sọ́ọ̀lù ló kórìíra Dáfídì.
“Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn. Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, ẹ̀yin olùfẹ́, àmọ́ ẹ fàyè sílẹ̀ fún ìrunú.”—Róòmù 12:18, 19
-