-
Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Lórí Òkè Kámẹ́lìÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 46
Ìṣẹ̀lẹ̀ Kan Lórí Òkè Kámẹ́lì
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọba tó jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ni kò dáa. Áhábù sì wà lára àwọn tó burú jù nínú wọn. Obìnrin abọ̀rìṣà kan tó ń jọ́sìn Báálì ló fẹ́. Jésíbẹ́lì lorúkọ obìnrin náà. Áhábù àti Jésíbẹ́lì mú káwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jọ́sìn Báálì, wọ́n sì tún pa àwọn wòlíì Jèhófà. Kí ni Jèhófà wá ṣe sọ́rọ̀ náà? Jèhófà rán wòlíì Èlíjà sí Áhábù.
Èlíjà sọ fún Ọba Áhábù pé òjò ò ní rọ̀ ní Ísírẹ́lì torí ìwà burúkú tó ń hù. Ohun tí Èlíjà sọ ṣẹ lóòótọ́, kò sí òjò fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta, ohun ọ̀gbìn kankan ò sì hù. Ebi wá ń pa àwọn èèyàn náà. Jèhófà tún rán Èlíjà pa dà sọ́dọ̀ Áhábù. Áhábù wá sọ fún un pé: ‘Oníjọ̀gbọ̀n ni ẹ́. Ìwọ lo fa gbogbo wàhálà yìí.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Èmi kọ́ ni mo ní kí òjò má rọ̀, ìwọ lo fà á torí pé Báálì lò ń sìn. A máa ṣe ohun kan tó máa jẹ́ ká mọ Ọlọ́run tòótọ́. Kó àwọn èèyàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtàwọn wòlíì Báálì wá sórí Òkè Kámẹ́lì.’
Bí gbogbo wọn ṣe pé jọ sórí òkè yẹn, Èlíjà sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e, àmọ́ tó bá jẹ́ Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ni pé, káwọn wòlíì Báálì tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (450) rú ẹbọ kí wọ́n sì ké pe ọlọ́run wọn, èmi náà máa rú ẹbọ, màá sì ké pe Jèhófà. Ọlọ́run tó bá finá jó ẹbọ ẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Àwọn èèyàn yẹn sì fara mọ́ ohun tó sọ.
Àwọn wòlíì Báálì gbé ẹbọ wọn sílẹ̀, ó wá ku kí Báálì fi iná jó ẹbọ náà. Látàárọ̀ títí di ọ̀sán ni wọ́n fi ń pè é, wọ́n ní: ‘Báálì dá wa lóhùn.’ Nígbà tí Báálì ò dáhùn, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní: ‘Ẹ pariwo gan-an, bóyá ó ń sùn lọ́wọ́, ó sì yẹ kẹ́nì kan lọ jí i.’ Ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn wòlíì Báálì ń pe ọlọ́run wọn, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá wọn lóhùn.
Èlíjà wá bẹ̀rẹ̀ sí í to igi jọ, ó gbé ẹran sórí ẹ̀, ó sì da omi lé e lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ dá mi lóhùn, káwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà mú kí iná já bọ́ látọ̀run, ó sì jó ẹbọ náà. Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: ‘Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!’ Èlíjà wá sọ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn wòlíì Báálì yẹn sá lọ o, ẹ mú wọn.’ Àwọn wòlíì Báálì tí wọ́n pa lọ́jọ́ yẹn jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (450).
Lẹ́yìn ìyẹn, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú bọ̀ látorí òkun, Èlíjà wá sọ fún Áhábù pé: ‘Òjò máa tó rọ̀, tètè máa lọ sílé.’ Bí ojú ọ̀run ṣe ṣú bolẹ̀ nìyẹn, atẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ gan-an, kí wọ́n tó mọ̀, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lójijì. Áhábù fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin ẹ̀ sáré gan-an. Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára débi pé ó sáré ju kẹ̀kẹ́ náà lọ! Ṣùgbọ́n, ṣé gbogbo ìṣòro Èlíjà ti wá tán nìyẹn? A máa rí i nínú orí tó kàn.
“Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.”—Sáàmù 83:18
-
-
Jèhófà Fún Èlíjà LókunÀwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 47
Jèhófà Fún Èlíjà Lókun
Nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ ohun tí Èlíjà ṣe fáwọn wòlíì Báálì, inú bí i gan-an. Ó wá ránṣẹ́ sí Èlíjà pé: ‘Tó bá máa fi dọ̀la, ìwọ náà á ti kú bí àwọn wòlíì Báálì tó o pa.’ Àyà Èlíjà wá bẹ̀rẹ̀ sí í já, bó ṣe sá lọ sí aṣálẹ̀ nìyẹn. Ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an, ó wá ń sinmi lábẹ́ igi kan, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jèhófà, wàhálà yìí ti pọ̀ jù, jẹ́ kí n kú.’ Ló bá sùn lọ lábẹ́ igi náà.
Bí Èlíjà ṣe ń sùn, áńgẹ́lì kan rọra jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Dìde, wá jẹun.’ Èlíjà rí búrẹ́dì kan lórí òkúta tó gbóná, ó sì tún rí ìgò omi kan. Ó jẹun, ó mu, ó sì pa dà sùn. Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà tún jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Jẹun, kó o lè lókun, torí pé ibi tó ò ń lọ jìn.’ Torí náà, Èlíjà tún jẹun sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíjà rìn fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru títí tó fi dé Òkè Hórébù. Nígbà tó débẹ̀, ó wọnú ihò àpáta kan, ó sì sùn síbẹ̀. Jèhófà wá bá a sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?’ Èlíjà sọ pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa ẹ́ tì, wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ, wọ́n sì ti pa àwọn wòlíì rẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n ti fẹ́ pa èmi náà báyìí.’
Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Lọ dúró sórí òkè yìí.’ Nígbà tó débẹ̀, atẹ́gùn kan kọ́kọ́ fẹ́ lórí òkè yẹn. Lẹ́yìn náà, ilẹ̀ mì, iná sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó. Níkẹyìn, Èlíjà gbọ́ ohùn kan tó rọra ń sọ̀rọ̀. Ó wá fi aṣọ bojú, ó sì jáde nínú ihò àpáta náà. Jèhófà wá bi í pé kí nìdí tó o fi sá lọ? Èlíjà sọ pé: ‘Èmi nìkan ló kù.’ Àmọ́, Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ìwọ nìkan kọ́ ló kù. Ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ló ṣì wà ní Ísírẹ́lì tó ń jọ́sìn mi. Torí náà, lọ kó o sì yan Èlíṣà ṣe wòlíì dípò rẹ.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíjà lọ ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ṣé o rò pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ṣe ohun tó fẹ́ kó o ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí òjò kò fi rọ̀ yẹn.
“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6
-